Ààyè ìgbéraga dà? Kò sí rárá. Nípa irú ìlànà wo ni kò fi sí mọ́? Nípa iṣẹ́ Òfin ni bí? Rárá o! Nípa ìlànà ti igbagbọ ni. Nítorí ohun tí a rí ni pé nípa igbagbọ ni Ọlọrun ń dá eniyan láre, kì í ṣe nípa pípa Òfin mọ́. Àbí ti àwọn Juu nìkan ni Ọlọrun, kì í ṣe ti àwọn orílẹ̀-èdè yòókù? Dájúdájú Ọlọrun àwọn Juu ati ti àwọn orílẹ̀-èdè yòókù ni. Nígbà tí ó jẹ́ pé Ọlọrun kanṣoṣo ni ó wà, òun ni ó sì ń dá àwọn tí ó kọlà láre nípa igbagbọ, tí ó tún ń dá àwọn tí kò kọlà láre nípa igbagbọ bákan náà. Ṣé Òfin wá di òtúbáńtẹ́ nítorí igbagbọ ni? Rárá o! A túbọ̀ fi ìdí Òfin múlẹ̀ ni.
Kà ROMU 3
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ROMU 3:27-31
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò