Rom 3:13-18

Rom 3:13-18 YBCV

Isà okú ti o ṣi silẹ li ọfun wọn; ahọn wọn ni nwọn fi nṣe itanjẹ; oró pamọlẹ mbẹ labẹ ète wọn: Ẹnu ẹniti o kún fun èpe ati fun ọ̀rọ kikoro: Ẹsẹ wọn yara lati ta ẹ̀jẹ silẹ: Iparun ati ipọnju wà li ọ̀na wọn: Ọ̀na alafia ni nwọn kò si mọ̀: Ibẹru Ọlọrun kò si niwaju wọn.