Rom 3:13-18
Rom 3:13-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Isà okú ti o ṣi silẹ li ọfun wọn; ahọn wọn ni nwọn fi nṣe itanjẹ; oró pamọlẹ mbẹ labẹ ète wọn: Ẹnu ẹniti o kún fun èpe ati fun ọ̀rọ kikoro: Ẹsẹ wọn yara lati ta ẹ̀jẹ silẹ: Iparun ati ipọnju wà li ọ̀na wọn: Ọ̀na alafia ni nwọn kò si mọ̀: Ibẹru Ọlọrun kò si niwaju wọn.
Rom 3:13-18 Yoruba Bible (YCE)
Ibojì tí ó yanu sílẹ̀ ni ọ̀nà ọ̀fun wọn, ẹ̀tàn kún ẹnu wọn; oró paramọ́lẹ̀ wà létè wọn; ẹnu wọn kún fún èpè ati ọ̀rọ̀ burúkú. Ẹsẹ̀ wọn yára láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀. Ọ̀nà jamba ati òṣì ni wọ́n ń rìn. Wọn kò mọ ọ̀nà alaafia. Kò sí ìbẹ̀rù Ọlọrun ní ọkàn wọn.”
Rom 3:13-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ibojì tí ó ṣí sílẹ̀ ní ọ̀fun wọn: ahọ́n wọn n sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.” “Oró paramọ́lẹ̀ ń bẹ lábẹ́ ètè wọn.” “Ẹnu ẹni tí ó kún fún èpè àti fún oró kíkorò.” “Ẹsẹ̀ wọn yára láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀: ìparun àti ìpọ́njú wà lọ́nà wọn. Ọ̀nà àlàáfíà ni wọn kò sì mọ̀:” “Ìbẹ̀rù Ọlọ́run kò sí níwájú wọn.”