O. Daf 32:5-8

O. Daf 32:5-8 YBCV

Emi jẹwọ ẹ̀ṣẹ mi fun ọ, ati ẹ̀ṣẹ mi li emi kò si fi pamọ́. Emi wipe, emi o jẹwọ ìrekọja mi fun Oluwa: iwọ si dari ẹbi ẹ̀ṣẹ mi jì. Nitori eyi li olukulùku ẹni ìwa-bi-ọlọrun yio ma gbadura si ọ ni igba ti a le ri ọ: nitõtọ ninu iṣan-omi nla, nwọn kì yio sunmọ ọdọ rẹ̀. Iwọ ni ibi ipamọ́ mi: iwọ o pa mi mọ́ kuro ninu iṣẹ́; iwọ o fi orin igbala yi mi ka kiri. Emi o fi ẹsẹ̀ rẹ le ọ̀na, emi o si kọ́ ọ li ọ̀na ti iwọ o rìn: emi o ma fi oju mi tọ́ ọ.