O. Daf 31:14-24

O. Daf 31:14-24 YBCV

Ṣugbọn emi gbẹkẹle ọ, Oluwa: emi ni, Iwọ li Ọlọrun mi. Igba mi mbẹ li ọwọ rẹ: gbà mi li ọwọ awọn ọta mi, ati li ọwọ awọn ti nṣe inunibini si mi, Ṣe oju rẹ ki o mọlẹ si iranṣẹ rẹ lara: gbà mi nitori ãnu rẹ. Máṣe jẹ ki oju ki o tì mi, Oluwa; nitori ti emi nkepè ọ; enia buburu ni ki oju ki o tì, awọn ni ki a mu dakẹ ni isa-okú. Awọn ète eke ni ki a mu dakẹ; ti nsọ̀rọ ohun buburu ni igberaga ati li ẹ̀gan si awọn olododo. Ore rẹ ti tobi to, ti iwọ fi ṣura dè awọn ti o bẹru rẹ: ore ti iwọ ti ṣe fun awọn ti o gbẹkẹle ọ niwaju awọn ọmọ enia! Iwọ o pa wọn mọ́ ni ibi ìkọkọ iwaju rẹ kuro ninu idimọlu awọn enia; iwọ o pa wọn mọ́ ni ìkọkọ ninu agọ kan kuro ninu ija ahọn. Olubukún ni Oluwa; nitori ti o ti fi iṣeun-ifẹ iyanu rẹ̀ hàn mi ni ilu olodi. Nitori ti mo ti wi ni ikanju mi pe, A ke mi kuro niwaju rẹ: ṣugbọn iwọ gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ mi nigbati mo kepè ọ. Ẹ fẹ Oluwa, gbogbo ẹnyin enia rẹ̀ mimọ́: Oluwa npa onigbagbọ́ mọ́, o si san a li ọ̀pọlọpọ fun ẹniti nṣe igberaga. Ẹ tujuka, yio si mu nyin li aiya le, gbogbo ẹnyin ti o ni ireti niti Oluwa.