O. Daf 31:14-24

O. Daf 31:14-24 Yoruba Bible (YCE)

Ṣugbọn, mo gbẹ́kẹ̀lé ọ, OLUWA, Mo ní, “Ìwọ ni Ọlọrun mi.” Ìgbà mi ń bẹ ní ọwọ́ rẹ; gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi, ati lọ́wọ́ àwọn tí ń lépa mi. Jẹ́ kí èmi iranṣẹ rẹ rí ojurere rẹ, gbà mí là, nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀. Má jẹ́ kí ojú tì mí, OLUWA, nítorí ìwọ ni mò ń ké pè. Jẹ́ kí ojú ti àwọn eniyan burúkú; jẹ́ kí ẹnu wọn wọ wòwò títí wọ ibojì. Jẹ́ kí àwọn òpùrọ́ yadi, àní àwọn tí ń fi ìgbéraga ati ẹ̀gàn sọ̀rọ̀ àìdára nípa olódodo. Háà! Ohun rere mà pọ̀ lọ́wọ́ rẹ o tí o ti sọ lọ́jọ̀ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ, tí o sì ti pèsè ní ìṣojú àwọn ọmọ eniyan, fún àwọn tí ó sá di ọ́. O fi ìyẹ́ apá rẹ ṣíji bò wọ́n; o pa wọ́n mọ́ kúrò ninu rìkíṣí àwọn eniyan; o sì pa wọ́n mọ́ lábẹ́ ààbò rẹ, kúrò lọ́wọ́ ẹnu àwọn ẹlẹ́jọ́ wẹ́wẹ́. Ẹni ìyìn ni OLUWA, nítorí pé, lọ́nà ìyanu, ó fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn mí, nígbà tí ilẹ̀ ká mi mọ́. Ẹ̀rù bà mí, mo sì sọ pé, “A lé mi jìnnà kúrò ní iwájú rẹ.” Ṣugbọn o gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi nígbà tí mo ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́. Ẹ fẹ́ràn OLUWA, gbogbo ẹ̀yin olódodo, OLUWA a máa ṣọ́ àwọn olóòótọ́, a sì máa san àlékún ẹ̀san fún àwọn agbéraga. Ẹ múra gírí, kí ẹ sì mọ́kàn le, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ gbẹ́kẹ̀lé OLUWA.

O. Daf 31:14-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ṣùgbọ́n èmí gbẹ́kẹ̀lé ọ, ìwọ OLúWA Mo sọ wí pé, “Ìwọ ní Ọlọ́run mi.” Ìgbà mi ń bẹ ní ọwọ́ rẹ; gbà mí kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀tá mi àti àwọn onínúnibíni. Jẹ́ kí ojú rẹ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí ìránṣẹ́ rẹ lára; Gbà mí nínú ìfẹ́ rẹ tí ó dúró ṣinṣin. Má ṣe jẹ́ kí ojú ki ó tì mí, OLúWA; nítorí pé mo ké pè ọ́; jẹ́ kí ojú kí ó ti ènìyàn búburú; jẹ́ kí wọ́n lọ pẹ̀lú ìdààmú sí isà òkú. Jẹ́ kí àwọn ètè irọ́ kí ó dákẹ́ jẹ́ẹ́, pẹ̀lú ìgbéraga àti ìkẹ́gàn, wọ́n sọ̀rọ̀ àfojúdi sí olódodo. Báwo ni títóbi oore rẹ̀ ti pọ̀ tó, èyí tí ìwọ ti ní ní ìpamọ́ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ, èyí tí ìwọ rọ̀jò rẹ̀ níwájú àwọn ènìyàn tí wọ́n fi ọ́ ṣe ibi ìsádi wọn. Ní abẹ́ ìbòòji iwájú rẹ ni ìwọ pa wọ́n mọ́ sí kúrò nínú ìdìmọ̀lù àwọn ènìyàn; ní ibùgbé rẹ, o mú wọn kúrò nínú ewu kúrò nínú ìjà ahọ́n. Olùbùkún ni OLúWA, nítorí pé ó ti fi àgbà ìyanu ìfẹ́ tí ó ní sí mi hàn, nígbà tí mo wà ní ìlú tí wọ́n rọ̀gbà yíká. Èmí ti sọ nínú ìdágìrì mi, “A gé mi kúrò ní ojú rẹ!” Síbẹ̀ ìwọ ti gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi fún àánú nígbà tí mo ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́. Ẹ fẹ́ OLúWA, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn rẹ̀ mímọ́! OLúWA pa olódodo mọ́, ó sì san án padà fún agbéraga ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Jẹ́ alágbára, yóò sì mú yín ní àyà le gbogbo ẹ̀yin tí ó dúró de OLúWA.