O. Daf 139:7-11

O. Daf 139:7-11 YBCV

Nibo li emi o gbe lọ kuro lọwọ ẹmi rẹ? tabi nibo li emi o sárè kuro niwaju rẹ? Bi emi ba gòke lọ si ọrun, iwọ wà nibẹ: bi emi ba si tẹ́ ẹni mi ni ipò okú, kiyesi i, iwọ wà nibẹ. Emi iba mu iyẹ-apa owurọ, ki emi si lọ joko niha opin okun; Ani nibẹ na li ọwọ rẹ yio fà mi, ọwọ ọtún rẹ yio si dì mi mu. Bi mo ba wipe, Njẹ ki òkunkun ki o bò mi mọlẹ; ki imọlẹ ki o di oru yi mi ka.