O. Daf 139:7-11
O. Daf 139:7-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nibo li emi o gbe lọ kuro lọwọ ẹmi rẹ? tabi nibo li emi o sárè kuro niwaju rẹ? Bi emi ba gòke lọ si ọrun, iwọ wà nibẹ: bi emi ba si tẹ́ ẹni mi ni ipò okú, kiyesi i, iwọ wà nibẹ. Emi iba mu iyẹ-apa owurọ, ki emi si lọ joko niha opin okun; Ani nibẹ na li ọwọ rẹ yio fà mi, ọwọ ọtún rẹ yio si dì mi mu. Bi mo ba wipe, Njẹ ki òkunkun ki o bò mi mọlẹ; ki imọlẹ ki o di oru yi mi ka.
O. Daf 139:7-11 Yoruba Bible (YCE)
Níbo ni mo lè sá lọ, tí ẹ̀mí rẹ kò ní sí níbẹ̀? Níbo ni mo lè sá gbà tí ojú rẹ kò ní tó mi? Ǹ báà gòkè re ọ̀run, o wà níbẹ̀! Bí mo sì tẹ́ ibùsùn mi sí isà òkú, n óo bá ọ níbẹ̀. Ǹ báà hu ìyẹ́, kí n fò lọ sí ibi ojúmọ́ ti ń mọ́ wá, kí n lọ pàgọ́ sí ibi tí òkun pin sí, níbẹ̀ gan-an, ọwọ́ rẹ ni yóo máa tọ́ mi, tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóo sì dì mí mú. Bí mo bá wí pé kí kìkì òkùnkùn bò mí mọ́lẹ̀, kí ọ̀sán di òru fún mi
O. Daf 139:7-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Níbo ní èmi yóò gbé lọ kúrò ni ọwọ́ ẹ̀mí rẹ? Tàbí níbo ni èmi yóò sáré kúrò níwájú rẹ? Bí èmi bá gòkè lọ sí ọ̀run, ìwọ wà níbẹ̀; bí èmí ba sì tẹ́ ẹní mi ní ipò òkú, kíyèsi i, ìwọ wà níbẹ̀ pẹ̀lú. Èmi ìbá mú ìyẹ́ apá òwúrọ̀, kí èmi sì lọ jókòó ní ìhà òpin Òkun; Àní, níbẹ̀ náà ni ọwọ́ rẹ̀ yóò fà mí ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì dì mímú. Bí mo bá wí pé, “Ǹjẹ́ kí òkùnkùn kí ó bò mí mọ́lẹ̀; kí ìmọ́lẹ̀ kí ó di òru yí mi ká.”