O. Daf 139:11-16

O. Daf 139:11-16 YBCV

Bi mo ba wipe, Njẹ ki òkunkun ki o bò mi mọlẹ; ki imọlẹ ki o di oru yi mi ka. Nitõtọ òkunkun kì iṣu lọdọ rẹ; ṣugbọn oru tàn imọlẹ bi ọsan: ati òkunkun ati ọsan, mejeji bakanna ni fun ọ. Nitori iwọ li o dá ọkàn mi: iwọ li o bò mi mọlẹ ni inu iya mi. Emi o yìn ọ; nitori tẹ̀ru-tẹ̀ru ati tiyanu-tiyanu li a dá mi: iyanu ni iṣẹ rẹ; eyinì li ọkàn mi si mọ̀ dajudaju. Ẹda ara mi kò pamọ kuro lọdọ rẹ, nigbati a da mi ni ìkọkọ, ti a si nṣiṣẹ mi li àrabara niha isalẹ ilẹ aiye. Oju rẹ ti ri ohun ara mi ti o wà laipé: a ti ninu iwe rẹ ni a ti kọ gbogbo wọn si, li ojojumọ li a nda wọn, nigbati ọkan wọn kò ti isi.