O. Daf 139:11-16
O. Daf 139:11-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bi mo ba wipe, Njẹ ki òkunkun ki o bò mi mọlẹ; ki imọlẹ ki o di oru yi mi ka. Nitõtọ òkunkun kì iṣu lọdọ rẹ; ṣugbọn oru tàn imọlẹ bi ọsan: ati òkunkun ati ọsan, mejeji bakanna ni fun ọ. Nitori iwọ li o dá ọkàn mi: iwọ li o bò mi mọlẹ ni inu iya mi. Emi o yìn ọ; nitori tẹ̀ru-tẹ̀ru ati tiyanu-tiyanu li a dá mi: iyanu ni iṣẹ rẹ; eyinì li ọkàn mi si mọ̀ dajudaju. Ẹda ara mi kò pamọ kuro lọdọ rẹ, nigbati a da mi ni ìkọkọ, ti a si nṣiṣẹ mi li àrabara niha isalẹ ilẹ aiye. Oju rẹ ti ri ohun ara mi ti o wà laipé: a ti ninu iwe rẹ ni a ti kọ gbogbo wọn si, li ojojumọ li a nda wọn, nigbati ọkan wọn kò ti isi.
O. Daf 139:11-16 Yoruba Bible (YCE)
Bí mo bá wí pé kí kìkì òkùnkùn bò mí mọ́lẹ̀, kí ọ̀sán di òru fún mi, òkùnkùn gan-an kò ṣú jù fún ọ; òru mọ́lẹ̀ bí ọ̀sán; lójú rẹ, ìmọ́lẹ̀ kò yàtọ̀ sí òkùnkùn. Nítorí ìwọ ni o dá inú mi, ìwọ ni o sọ mí di odidi ní inú ìyá mi. Mo yìn ọ́, nítorí pé ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ ati ẹni ìyanu ni ọ́; ìyanu ni iṣẹ́ ọwọ́ rẹ! O mọ̀ mí dájú. Nígbà tí à ń ṣẹ̀dá egungun mi lọ́wọ́ ní ìkọ̀kọ̀, tí ẹlẹ́dàá ṣẹ̀ṣẹ̀ ń ṣọnà sí mi lára ní àṣírí, kò sí èyí tí ó pamọ́ fún ọ. Kí á tó dá mi tán ni o ti rí mi, o ti kọ iye ọjọ́ tí a pín fún mi sinu ìwé rẹ, kí ọjọ́ ayé mi tilẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ rárá.
O. Daf 139:11-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bí mo bá wí pé, “Ǹjẹ́ kí òkùnkùn kí ó bò mí mọ́lẹ̀; kí ìmọ́lẹ̀ kí ó di òru yí mi ká.” Nítòótọ́ òkùnkùn kì í ṣú lọ́dọ̀ rẹ; ṣùgbọ́n òru tan ìmọ́lẹ̀ bí ọ̀sán; àti òkùnkùn àti ọ̀sán, méjèèjì bákan náà ní fún ọ. Nítorí ìwọ ni ó dá ọkàn mi; ìwọ ni ó bò mí mọ́lẹ̀ nínú ìyá mi. Èmi yóò yìn ọ, nítorí tẹ̀rù tẹ̀rù àti tìyanu tìyanu ní a dá mi; ìyanu ní iṣẹ́ rẹ; èyí nì ni ọkàn mi sì mọ̀ dájúdájú Ẹ̀dá ara mi kò pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ rẹ, nígbà tí a dá mi ní ìkọ̀kọ̀. Tí a sì ń ṣiṣẹ́ ní àràbarà ní ìhà ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé, ojú rẹ ti rí ohun ara mi nígbà tí a kò tí ì ṣe mí pé: àti nínú ìwé rẹ ni a ti kọ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sí, ní ọjọ́ tí a dá wọn, nígbà tí wọn kò tilẹ̀ tí ì sí.