O. Daf 106:1-5

O. Daf 106:1-5 YBCV

Ẹ fi iyìn fun Oluwa! Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa: nitoriti o ṣeun: nitoriti ti ãnu rẹ̀ duro lailai. Tali o le sọ̀rọ iṣẹ agbara Oluwa? tali o le fi gbogbo iyìn rẹ̀ hàn? Ibukún ni fun awọn ti npa idajọ mọ́, ati ẹniti nṣe ododo ni igbagbogbo. Oluwa, fi oju-rere ti iwọ ni si awọn enia rẹ ṣe iranti mi: fi igbala rẹ bẹ̀ mi wò. Ki emi ki o le ri ire awọn ayanfẹ rẹ, ki emi ki o le yọ̀ ninu ayọ̀ orilẹ-ède rẹ, ki emi ki o le ma ṣogo pẹlu awọn enia ilẹ-ini rẹ.