O. Daf 106:1-5
O. Daf 106:1-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ fi iyìn fun Oluwa! Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa: nitoriti o ṣeun: nitoriti ti ãnu rẹ̀ duro lailai. Tali o le sọ̀rọ iṣẹ agbara Oluwa? tali o le fi gbogbo iyìn rẹ̀ hàn? Ibukún ni fun awọn ti npa idajọ mọ́, ati ẹniti nṣe ododo ni igbagbogbo. Oluwa, fi oju-rere ti iwọ ni si awọn enia rẹ ṣe iranti mi: fi igbala rẹ bẹ̀ mi wò. Ki emi ki o le ri ire awọn ayanfẹ rẹ, ki emi ki o le yọ̀ ninu ayọ̀ orilẹ-ède rẹ, ki emi ki o le ma ṣogo pẹlu awọn enia ilẹ-ini rẹ.
O. Daf 106:1-5 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ yin OLUWA! Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, nítorí pé ó ṣeun nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae. Ta ló lè sọ iṣẹ́ agbára OLUWA tán? Ta ló sì lè fi gbogbo ìyìn rẹ̀ hàn? Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ń ṣe ẹ̀tọ́, àwọn tí ń ṣe ohun tí ó tọ̀nà nígbà gbogbo. Ranti mi, OLUWA, nígbà tí o bá ń ṣí ojurere wo àwọn eniyan rẹ. Ràn mí lọ́wọ́ nígbà tí o bá ń gbà wọ́n là. Kí n lè rí ire àwọn àyànfẹ́ rẹ kí n lè ní ìpín ninu ayọ̀ àwọn eniyan rẹ, kí n sì lè máa ṣògo pẹlu àwọn tí ó jẹ́ eniyan ìní rẹ.
O. Daf 106:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Yin OLúWA! Ẹ fi ìyìn fún OLúWA, nítorí tí ó ṣeun. Ẹ fi ọpẹ́ fún OLúWA nítorí tí ó ṣeun; Nítorí tí ìfẹ́ rẹ̀ dúró láéláé. Ta ni ó lè ròyìn iṣẹ́ agbára OLúWA, ta ní lè sọ nípa ìyìn rẹ̀? Ìbùkún ni fún àwọn tí ń pa ìdájọ́ mọ́? Ẹni tí n ṣe ohun tí ó tọ́. Rántí mi, OLúWA, Nígbà tí o bá fi ojúrere rẹ hàn, wá sí ìhà mi nígbà tí ìwọ bá gbà wọ́n, Kí èmi kí ó lè jẹ ìgbádùn àlàáfíà àwọn tí ìwọ ti yàn, kí èmi kí ó sì darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn, ìní rẹ láti jọ yìn ọ́ lógo.