O. Daf 103:13-18

O. Daf 103:13-18 YBCV

Bi baba ti iṣe iyọ́nu si awọn ọmọ, bẹ̃li Oluwa nṣe iyọ́nu si awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀. Nitori ti o mọ̀ ẹda wa; o ranti pe erupẹ ni wa. Bi o ṣe ti enia ni, ọjọ rẹ̀ dabi koriko: bi itana eweko igbẹ bẹ̃li o gbilẹ. Nitori ti afẹfẹ fẹ kọja lọ lori rẹ̀, kò sì si mọ́; ibujoko rẹ̀ kò mọ̀ ọ mọ́. Ṣugbọn ãnu Oluwa lati aiyeraiye ni lara awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀, ati ododo rẹ̀ lati ọmọ de ọmọ: Si awọn ti o pa majẹmu rẹ̀ mọ́, ati si awọn ti o ranti ofin rẹ̀ lati ṣe wọn.