O. Daf 103:13-18
O. Daf 103:13-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bi baba ti iṣe iyọ́nu si awọn ọmọ, bẹ̃li Oluwa nṣe iyọ́nu si awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀. Nitori ti o mọ̀ ẹda wa; o ranti pe erupẹ ni wa. Bi o ṣe ti enia ni, ọjọ rẹ̀ dabi koriko: bi itana eweko igbẹ bẹ̃li o gbilẹ. Nitori ti afẹfẹ fẹ kọja lọ lori rẹ̀, kò sì si mọ́; ibujoko rẹ̀ kò mọ̀ ọ mọ́. Ṣugbọn ãnu Oluwa lati aiyeraiye ni lara awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀, ati ododo rẹ̀ lati ọmọ de ọmọ: Si awọn ti o pa majẹmu rẹ̀ mọ́, ati si awọn ti o ranti ofin rẹ̀ lati ṣe wọn.
O. Daf 103:13-18 Yoruba Bible (YCE)
Bí baba ti máa ń ṣàánú àwọn ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni OLUWA máa ń ṣàánú àwọn tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀. Nítorí ó mọ ẹ̀dá wa; ó ranti pé erùpẹ̀ ni wá. Ọjọ́ ayé ọmọ eniyan dàbí ti koríko, eniyan a sì máa gbilẹ̀ bí òdòdó inú igbó; ṣugbọn bí afẹ́fẹ́ bá ti fẹ́ kọjá lórí rẹ̀, á rẹ̀ dànù, ààyè rẹ̀ kò sì ní ranti rẹ̀ mọ́. Ṣugbọn títí ayé ni ìfẹ́ OLUWA tí kì í yẹ̀, sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀, òdodo rẹ̀ wà lára arọmọdọmọ wọn. Ó wà lára àwọn tí ó ń pa majẹmu rẹ̀ mọ́, tí wọn sì ń ranti láti pa òfin rẹ̀ mọ́.
O. Daf 103:13-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bí baba ti ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni OLúWA ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀; Nítorí tí ó mọ dídá wa, ó rántí pé erùpẹ̀ ni wá. Bí ó ṣe ti ènìyàn ni, ọjọ́ rẹ̀ dàbí koríko, ó gbilẹ̀ bí ìtànná ewéko igbó; Afẹ́fẹ́ fẹ́ kọjá lọ lórí rẹ̀, kò sì rántí ibùjókòó rẹ̀ mọ́. Ṣùgbọ́n láti ayérayé ni ìfẹ́ OLúWA ti wà pẹ̀lú àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀, àti òdodo rẹ̀ wà láti ọmọdọ́mọ Sí àwọn tí ó pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́ àti àwọn tí ó rántí òfin rẹ̀ láti ṣe wọ́n.