ỌMỌ mi, bi iwọ ba ṣe onigbọwọ fun ọrẹ́ rẹ, bi iwọ ba jẹ́ ẹ̀jẹ́ fun ajeji enia.
Bi a ba fi ọ̀rọ ẹnu rẹ dẹkùn fun ọ, bi a ba fi ọ̀rọ ẹnu rẹ mu ọ.
Njẹ, sa ṣe eyi, ọmọ mi, ki o si gbà ara rẹ silẹ nigbati iwọ ba bọ si ọwọ ọrẹ́ rẹ; lọ, rẹ ara rẹ silẹ, ki iwọ ki o si tù ọrẹ́ rẹ.
Máṣe fi orun fun oju rẹ, tabi õgbe fun ipenpeju rẹ.
Gbà ara rẹ bi abo agbọnrin li ọwọ ọdẹ, ati bi ẹiyẹ li ọwọ apẹiyẹ.
Tọ ẽrùn lọ, iwọ ọlẹ: kiyesi iṣe rẹ̀ ki iwọ ki o si gbọ́n:
Ti kò ni onidajọ, alabojuto, tabi alakoso.
Ti npese onjẹ rẹ̀ ni igba-ẹ̀run, ti o si nkó onjẹ rẹ̀ jọ ni ìgba ikore.
Ọlẹ, iwọ o ti sùn pẹ to? nigbawo ni iwọ o dide kuro ninu orun rẹ?
Orun diẹ si i, õgbe diẹ si i, ikawọkòpọ lati sùn diẹ:
Bẹ̃ni òṣi rẹ yio de bi ẹniti nrìn àjo, ati aini rẹ bi ọkunrin ti o hamọra ogun.
Enia-kenia, ọkunrin buburu, ti o nrìn ti on ti ẹnu arekereke.
O nṣẹju rẹ̀, o nfi ẹsẹ rẹ̀ sọ̀rọ, o nfi ika rẹ̀ ṣe ajuwe;
Arekereke mbẹ li aiya rẹ̀, o humọ ìwa-ika nigbagbogbo; o ndá ija silẹ.
Nitorina ni ipọnju rẹ̀ yio de si i lojiji; ojiji ni yio ṣẹ́ laini atunṣe.
Ohun mẹfa li Oluwa korira: nitõtọ, meje li o ṣe irira fun ọkàn rẹ̀:
Oju igberaga, ète eke, ati ọwọ ti nta ẹ̀jẹ alaiṣẹ silẹ,
Aiya ti nhumọ buburu, ẹsẹ ti o yara ni ire sisa si ìwa-ika,
Ẹlẹri eke ti nsọ eke jade, ati ẹniti ndá ìja silẹ larin awọn arakunrin.
Ọmọ mi, pa aṣẹ baba rẹ mọ́, ki iwọ ki o má si ṣe kọ̀ ofin iya rẹ silẹ:
Dì wọn mọ aiya rẹ nigbagbogbo, ki iwọ ki o si so o mọ ọrùn rẹ.
Nigbati iwọ ba nrìn, yio ma ṣe amọ̀na rẹ; nigbati iwọ ba sùn, yio ma ṣọ ọ; nigbati iwọ ba si ji, yio si ma ba ọ sọ̀rọ.
Nitoripe aṣẹ ni fitila; ofin si ni imọlẹ; ati ibawi ẹkọ́ li ọ̀na ìye