Owe 6:1-23
Owe 6:1-23 Bibeli Mimọ (YBCV)
ỌMỌ mi, bi iwọ ba ṣe onigbọwọ fun ọrẹ́ rẹ, bi iwọ ba jẹ́ ẹ̀jẹ́ fun ajeji enia. Bi a ba fi ọ̀rọ ẹnu rẹ dẹkùn fun ọ, bi a ba fi ọ̀rọ ẹnu rẹ mu ọ. Njẹ, sa ṣe eyi, ọmọ mi, ki o si gbà ara rẹ silẹ nigbati iwọ ba bọ si ọwọ ọrẹ́ rẹ; lọ, rẹ ara rẹ silẹ, ki iwọ ki o si tù ọrẹ́ rẹ. Máṣe fi orun fun oju rẹ, tabi õgbe fun ipenpeju rẹ. Gbà ara rẹ bi abo agbọnrin li ọwọ ọdẹ, ati bi ẹiyẹ li ọwọ apẹiyẹ. Tọ ẽrùn lọ, iwọ ọlẹ: kiyesi iṣe rẹ̀ ki iwọ ki o si gbọ́n: Ti kò ni onidajọ, alabojuto, tabi alakoso. Ti npese onjẹ rẹ̀ ni igba-ẹ̀run, ti o si nkó onjẹ rẹ̀ jọ ni ìgba ikore. Ọlẹ, iwọ o ti sùn pẹ to? nigbawo ni iwọ o dide kuro ninu orun rẹ? Orun diẹ si i, õgbe diẹ si i, ikawọkòpọ lati sùn diẹ: Bẹ̃ni òṣi rẹ yio de bi ẹniti nrìn àjo, ati aini rẹ bi ọkunrin ti o hamọra ogun. Enia-kenia, ọkunrin buburu, ti o nrìn ti on ti ẹnu arekereke. O nṣẹju rẹ̀, o nfi ẹsẹ rẹ̀ sọ̀rọ, o nfi ika rẹ̀ ṣe ajuwe; Arekereke mbẹ li aiya rẹ̀, o humọ ìwa-ika nigbagbogbo; o ndá ija silẹ. Nitorina ni ipọnju rẹ̀ yio de si i lojiji; ojiji ni yio ṣẹ́ laini atunṣe. Ohun mẹfa li Oluwa korira: nitõtọ, meje li o ṣe irira fun ọkàn rẹ̀: Oju igberaga, ète eke, ati ọwọ ti nta ẹ̀jẹ alaiṣẹ silẹ, Aiya ti nhumọ buburu, ẹsẹ ti o yara ni ire sisa si ìwa-ika, Ẹlẹri eke ti nsọ eke jade, ati ẹniti ndá ìja silẹ larin awọn arakunrin. Ọmọ mi, pa aṣẹ baba rẹ mọ́, ki iwọ ki o má si ṣe kọ̀ ofin iya rẹ silẹ: Dì wọn mọ aiya rẹ nigbagbogbo, ki iwọ ki o si so o mọ ọrùn rẹ. Nigbati iwọ ba nrìn, yio ma ṣe amọ̀na rẹ; nigbati iwọ ba sùn, yio ma ṣọ ọ; nigbati iwọ ba si ji, yio si ma ba ọ sọ̀rọ. Nitoripe aṣẹ ni fitila; ofin si ni imọlẹ; ati ibawi ẹkọ́ li ọ̀na ìye
Owe 6:1-23 Yoruba Bible (YCE)
Ọmọ mi, bí o bá ṣe onídùúró fún aládùúgbò rẹ, tí o jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún àjèjì, tí o bá bọ́ sinu tàkúté tí o fi ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ dẹ fún ara rẹ, tí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ sì ti kó bá ọ, o ti bọ́ sọ́wọ́ aládùúgbò rẹ. Nítorí náà báyìí ni kí o ṣe, ọmọ mi, kí o lè gba ara rẹ là: lọ bá a kíákíá, kí o sì bẹ̀ ẹ́. Má sùn, má sì tòògbé, gba ara rẹ sílẹ̀ bí àgbọ̀nrín tíí gba ara rẹ̀ sílẹ̀ lọ́wọ́ ọdẹ, àní, bí ẹyẹ tíí ṣe, tíí fi í bọ́ lọ́wọ́ pẹyẹpẹyẹ. Ìwọ ọ̀lẹ, tọ èèrùn lọ, ṣàkíyèsí ìṣe rẹ̀, kí o sì kọ́gbọ́n. Ẹ̀dá tí kò ní olórí, tabi alabojuto, tabi aláṣẹ sibẹsibẹ, a máa tọ́jú oúnjẹ rẹ̀ ní àkókò ẹ̀ẹ̀rùn; a sì máa kó oúnjẹ jọ, ní àkókò ìkórè. O óo ti sùn pẹ́ tó, ìwọ ọ̀lẹ? Ìgbà wo ni o óo tají lójú oorun? Oorun díẹ̀, òògbé díẹ̀, ìkáwọ́gbera díẹ̀ láti sinmi, yóo jẹ́ kí òṣì dé bá ọ, bí ọlọ́ṣà dé bá eniyan. Àìní yóo sì dé bá ọ bíi jagunjagun dé báni. Eniyan lásán, ìkà eniyan, a máa rìn káàkiri, a máa sọ̀rọ̀ àrékérekè, bí ó ti ń ṣẹ́jú, bẹ́ẹ̀ ni ó ń jansẹ̀ mọ́lẹ̀, tí ó sì ń fi ìka ṣe àpèjúwe. Ó ń fi inú burúkú pète ibi, ó sì ń fi ojoojumọ dá ìjà sílẹ̀, nítorí náà, ibi yóo dé bá a lójijì, yóo parun kíá láìsí àtúnṣe. Àwọn nǹkan mẹfa kan wà tí OLUWA kò fẹ́: wọ́n tilẹ̀ tó meje tí ó jẹ́ ohun ìríra fún un: Ìgbéraga, irọ́ pípa, ẹni tí ń déédé pa aláìṣẹ̀, ọkàn tí ń pète ìkà, ẹsẹ̀ tí ń sáré sí ibi, ẹlẹ́rìí èké tí ẹnu rẹ̀ kún fún irọ́, ati ẹni tí ń dá ìjà sílẹ̀ láàrin eniyan. Ọmọ mi, pa òfin baba rẹ mọ́, má sì ṣe kọ ẹ̀kọ́ ìyá rẹ sílẹ̀. Fi wọ́n sọ́kàn nígbà gbogbo, kí o sì so wọ́n mọ́ ọrùn rẹ. Nígbà tí o bá ń lọ, wọn yóo máa tọ́ ọ, bí o bá sùn, wọn yóo máa ṣọ́ ọ, bí o bá jí, wọn yóo máa bá ọ sọ̀rọ̀. Nítorí fìtílà ni òfin, ìmọ́lẹ̀ ni ẹ̀kọ́, ìbáwí sì jẹ́ ọ̀nà ìyè
Owe 6:1-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọmọ mi, bí ìwọ bá ṣe onídùúró fún aládùúgbò rẹ, bí ìwọ bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún àjèjì ènìyàn, bí a bá ti fi ọ̀rọ̀ tí ó sọ dẹkùn mú ọ, tí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ ti kó ọ sí pàkúté, Nígbà náà, ṣe èyí, ìwọ ọmọ mi, láti gba ara rẹ níwọ̀n bí o ti kó ṣọ́wọ́ aládùúgbò rẹ: lọ kí o sì rẹ ara rẹ sílẹ̀; bẹ aládùúgbò rẹ dáradára Má ṣe jẹ́ kí oorun kí ó kùn ọ́, tàbí kí o tilẹ̀ tòògbé rárá. Gba ara rẹ sílẹ̀, bí abo èsúró kúrò lọ́wọ́ ọdẹ, bí ẹyẹ kúrò nínú okùn àwọn pẹyẹpẹyẹ. Tọ èèrà lọ, ìwọ ọ̀lẹ kíyèsi ìṣe rẹ̀, kí o sì gbọ́n! Kò ní olùdarí, kò sí alábojútó tàbí ọba, síbẹ̀, a kó ìpèsè rẹ̀ jọ ní àsìkò òjò yóò sì kó oúnjẹ rẹ̀ jọ ní àsìkò ìkórè. Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò dùbúlẹ̀, ìwọ ọ̀lẹ? Nígbà wo ni ìwọ yóò jí kúrò lójú oorun rẹ? Oorun díẹ̀, òògbé díẹ̀, ìkáwọ́gbera láti sinmi díẹ̀ Òsì yóò sì wá sórí rẹ bí ìgárá ọlọ́ṣà àti àìní bí adigunjalè. Ènìyànkénìyàn àti ènìyàn búburú, tí ń ru ẹnu àrékérekè káàkiri, tí ó ń ṣẹ́jú pàkòpàkò, ó ń fi ẹsẹ̀ rẹ̀ sọ̀rọ̀ ó sì ń fi ìka ọwọ́ rẹ̀ júwe, tí ó ń pète búburú pẹ̀lú ẹ̀tàn nínú ọkàn rẹ̀ ìgbà gbogbo ni ó máa ń dá ìjà sílẹ̀. Nítorí náà ìdààmú yóò dé bá a ní ìṣẹ́jú akàn; yóò parun lójijì láìsí àtúnṣe. Àwọn ohun mẹ́fà wà tí OLúWA kórìíra, ohun méje ní ó jẹ́ ìríra sí i: Ojú ìgbéraga, Ahọ́n tó ń parọ́ ọwọ́ tí ń ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀, ọkàn tí ń pète ohun búburú, ẹsẹ̀ tí ó yára láti sáré sínú ìwà ìkà, Ajẹ́rìí èké tí ń tú irọ́ jáde lẹ́nu àti ènìyàn tí ń dá ìjà sílẹ̀ láàrín àwọn ọmọ ìyá kan. Ọmọ mi, pa àṣẹ baba rẹ mọ́ má sì ṣe kọ ẹ̀kọ́ ìyá rẹ sílẹ̀. Jẹ́ kí wọn wà nínú ọkàn rẹ láéláé so wọ́n mọ́ ọrùn rẹ Nígbà tí ìwọ bá ń rìn, wọn yóò ṣe amọ̀nà rẹ; nígbà tí ìwọ bá sùn, wọn yóò máa ṣe olùṣọ́ rẹ; nígbà tí o bá jí, wọn yóò bá ọ sọ̀rọ̀. Nítorí àwọn àṣẹ yìí jẹ́ fìtílà, ẹ̀kọ́ yìí jẹ́ ìmọ́lẹ̀, àti ìtọ́nisọ́nà ti ìbáwí ni ọ̀nà sí ìyè.