Owe 27:23-27

Owe 27:23-27 YBCV

Iwọ ma ṣaniyan ati mọ̀ ìwa agbo-ẹran rẹ, ki iwọ ki o si bojuto awọn ọwọ-ẹran rẹ. Nitoripe ọrọ̀ ki iwà titi lai: ade a ha si ma wà de irandiran? Koriko yọ, ati ọmunú koriko fi ara han, ati ewebẹ̀ awọn òke kojọ pọ̀. Awọn ọdọ-agutan ni fun aṣọ rẹ, awọn obukọ si ni iye-owo oko. Iwọ o si ni wàra ewurẹ to fun onjẹ rẹ, fun onjẹ awọn ara ile rẹ, ati fun onjẹ awọn iranṣẹ-birin rẹ.