Owe 27:23-27
Owe 27:23-27 Bibeli Mimọ (YBCV)
Iwọ ma ṣaniyan ati mọ̀ ìwa agbo-ẹran rẹ, ki iwọ ki o si bojuto awọn ọwọ-ẹran rẹ. Nitoripe ọrọ̀ ki iwà titi lai: ade a ha si ma wà de irandiran? Koriko yọ, ati ọmunú koriko fi ara han, ati ewebẹ̀ awọn òke kojọ pọ̀. Awọn ọdọ-agutan ni fun aṣọ rẹ, awọn obukọ si ni iye-owo oko. Iwọ o si ni wàra ewurẹ to fun onjẹ rẹ, fun onjẹ awọn ara ile rẹ, ati fun onjẹ awọn iranṣẹ-birin rẹ.
Owe 27:23-27 Yoruba Bible (YCE)
Rí i dájú pé o mọ̀ bí agbo ẹran rẹ ti rí, sì máa tọ́jú ọ̀wọ́ ẹran rẹ dáradára; nítorí ọrọ̀ kì í pẹ́ lọ títí, kí adé pẹ́ lórí kì í ṣe láti ìrandíran. Lẹ́yìn tí a bá gé koríko, tí koríko tútù mìíràn sì hù, tí a bá kó koríko tí a gé lára àwọn òkè wálé, o óo rí irun aguntan fi hun aṣọ, o óo sì lè fi owó tí o bá pa lórí àwọn ewúrẹ́ rẹ ra ilẹ̀. O óo rí omi wàrà ewúrẹ́ rẹ fún, tí o óo máa rí mu, ìwọ ati ìdílé rẹ, ati àwọn iranṣẹbinrin rẹ pẹlu.
Owe 27:23-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
Rí i dájú pé o mọ ipò tí àwọn agbo àgùntàn rẹ wà bojútó àwọn agbo màlúù rẹ dáradára; nítorí ọrọ̀ kì í pẹ́ lọ títí adé kì í sì í wà lórí títí láéláé. Nígbà tí a bá kó koríko, ewéko tuntun yóò sì hù jáde, a ó sì kó koríko àwọn orí òkè wọlé àwọn àgùntàn yóò pèsè aṣọ fún ọ, àti ewúrẹ́ yóò pèsè owó oko. Ìwọ yóò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàrà ewúrẹ́ láti bọ́ ọ àti ìdílé rẹ àti láti tọ́jú àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ.