Filp 3:3-6

Filp 3:3-6 YBCV

Nitori awa ni onilà, ti nsìn Ọlọrun nipa ti Ẹmí, awa si nṣogo ninu Kristi Jesu, awa kò si ni igbẹkẹle ninu ẹran-ara; Bi emi tikarami tilẹ ni igbẹkẹle ninu ara. Bi ẹnikẹni ba rò pe on ni igbẹkẹle ninu ara, temi tilẹ ju: Ẹniti a kọ nilà ni ijọ kẹjọ, lati inu kukuté Israeli wá, lati inu ẹ̀ya Benjamini, Heberu lati inu Heberu wá; niti ofin, Farisi li emi; Niti itara, emi nṣe inunibini si ijọ; niti ododo ti o wà ninu ofin, mo jẹ alailẹgan.