Nítorí àwa gan-an ni ọ̀kọlà, àwa tí à ń sin Ọlọrun nípa Ẹ̀mí, tí à ń ṣògo ninu Kristi Jesu, tí a kò gbára lé nǹkan ti ara, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti gbára lé nǹkan ti ara nígbà kan rí. Bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun ní ìdí láti fi gbára lé nǹkan ti ara, mo ní i ju ẹnikẹ́ni lọ. Ní ọjọ́ kẹjọ ni wọ́n kọ mí nílà. Ọmọ Israẹli ni mí, láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini, Heberu paraku ni mí. Nípa ti Òfin Mose, Farisi ni mí. Ní ti ìtara ninu ẹ̀sìn, mo ṣe inúnibíni sí ìjọ Kristi. Ní ti òdodo nípa iṣẹ́ Òfin, n kò kùnà níbìkan.
Kà FILIPI 3
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: FILIPI 3:3-6
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò