Filp 1:22-26

Filp 1:22-26 YBCV

Ṣugbọn bi lati wà lãye ninu ara ba jẹ eso iṣẹ mi, nigbana ohun ti emi o yàn, emi kò mọ. Ṣugbọn emi mbẹ ni iyemeji, mo ni ifẹ lati lọ ati lati wà lọdọ Kristi; nitori o dara pupọ ju: Sibẹ lati wà ninu ara jẹ anfani nitori ti nyin. Bi eyi si ti da mi loju, mo mọ̀ pe emi ó duro, emi ó si mã bá gbogbo nyin gbé fun ilọsiwaju ati ayọ̀ nyin ninu igbagbọ; Ki iṣogo nyin ki o le di pupọ gidigidi ninu Jesu Kristi ninu mi nipa ipada wá mi sọdọ nyin.