Filp 1:22-26
Filp 1:22-26 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn bi lati wà lãye ninu ara ba jẹ eso iṣẹ mi, nigbana ohun ti emi o yàn, emi kò mọ. Ṣugbọn emi mbẹ ni iyemeji, mo ni ifẹ lati lọ ati lati wà lọdọ Kristi; nitori o dara pupọ ju: Sibẹ lati wà ninu ara jẹ anfani nitori ti nyin. Bi eyi si ti da mi loju, mo mọ̀ pe emi ó duro, emi ó si mã bá gbogbo nyin gbé fun ilọsiwaju ati ayọ̀ nyin ninu igbagbọ; Ki iṣogo nyin ki o le di pupọ gidigidi ninu Jesu Kristi ninu mi nipa ipada wá mi sọdọ nyin.

Filp 1:22-26 Yoruba Bible (YCE)
Bí mo bá wà láàyè ninu ẹran-ara, iṣẹ́ tí ó lérè ni ó jẹ́ fún mi. N kò tilẹ̀ mọ èyí tí ǹ bá yàn. Ọkàn mi ń ṣe meji; ọkàn mi kan fẹ́ pé kí á dá mi sílẹ̀, kí n lọ sọ́dọ̀ Jesu, nítorí èyí ni ó dára jùlọ. Ṣugbọn ó tún ṣàǹfààní bí mo bá wà láàyè ninu ẹran-ara, nítorí tiyín. Èyí dá mi lójú, nítorí náà mo mọ̀ pé n óo wà láàyè. Bí mo bá wà ní ọ̀dọ̀ gbogbo yín, yóo mú ìlọsíwájú ati ayọ̀ ninu igbagbọ wá fun yín. Èyí yóo mú kí ìṣògo yín ninu Kristi Jesu lè pọ̀ sí i nítorí mi, nígbà tí mo bá tún yọ si yín.
Filp 1:22-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n bí èmi bá le è ṣe iṣẹ́ ti ó ni àpẹẹrẹ nípa wíwà láààyè nínú ara, ṣùgbọ́n ohun ti èmi ó yàn, èmi kò mọ̀. Ṣùgbọ́n èmi n ṣiyèméjì, nítorí ti èmi fẹ́ láti lọ kúrò nínú ayé yìí, láti wà lọ́dọ̀ Kristi; nítorí ó dára púpọ̀ jù: Síbẹ̀ láti wà láààyè jẹ́ àǹfààní nítorí tiyín. Bí èyí sì ti dá mi lójú, mo mọ̀ pé èmi ó dúró, èmi ó sì máa wà pẹ̀lú yín fún ìtẹ̀síwájú àti ayọ̀ yín nínú ìgbàgbọ́, kí ìṣògo yín kí ó lè di púpọ̀ gidigidi nínú Jesu Kristi, àti nínú mi nípa ìpadà wá mi sọ́dọ̀ yín.