O SI ṣe lẹhin àrun na, ni OLUWA sọ fun Mose ati fun Eleasari alufa ọmọ Aaroni pe,
Kà iye gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gẹgẹ bi ile awọn baba wọn, gbogbo awọn ti o le lọ si ogun ni Israeli.
Mose ati Eleasari alufa si sọ fun wọn ni pẹtẹlẹ̀ Moabu, lẹba Jordani leti Jeriko pe,
Ẹ kà iye awọn enia na, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose, ati fun awọn ọmọ Israeli, ti o ti ilẹ Egipti jade wá.
Reubeni, akọ́bi Israeli: awọn ọmọ Reubeni; Hanoki, lati ọdọ ẹniti idile awọn ọmọ Hanoki ti wá: ti Pallu, idile awọn ọmọ Pallu:
Ti Hesroni, idile awọn ọmọ Hesroni: ti Karmi, idile awọn ọmọ Karmi.
Wọnyi ni idile awọn ọmọ Reubeni: awọn ti a si kà ninu wọn jẹ́ ẹgba mọkanlelogun o le ẹgbẹsan o din ãdọrin.
Ati awọn ọmọ Pallu; Eliabu.
Ati awọn ọmọ Eliabu; Nemueli, ati Datani, ati Abiramu. Eyi ni Datani ati Abiramu na, ti nwọn lí okiki ninu ijọ, ti nwọn bá Mose ati Aaroni jà ninu ẹgbẹ Kora, nigbati nwọn bá OLUWA jà.
Ti ilẹ si là ẹnu rẹ̀, ti o si gbe wọn mì pọ̀ pẹlu Kora, nigbati ẹgbẹ na fi kú, nigbati iná fi run awọn ãdọtalerugba ọkunrin, ti nwọn si di àmi kan.
Ṣugbọn awọn ọmọ Kora kò kú.
Awọn ọmọ Simeoni bi idile wọn: ti Nemueli, idile Nemueli: ti Jamini, idile Jamini: ti Jakini, idile Jakini:
Ti Sera, idile Sera: ti Ṣaulu, idile Ṣaulu.
Wọnyi ni idile awọn ọmọ Simeoni, ẹgba mọkanla o le igba.
Awọn ọmọ Gadi bi idile wọn: ti Sefoni, idile Sefoni: ti Haggi, idile Haggi: ti Ṣuni, idile Ṣuni:
Ti Osni, idile Osni: ti Eri, idile Eri:
Ti Arodu, idile Arodu: ti Areli, idile Areli.
Wọnyi ni idile awọn ọmọ Gadi gẹgẹ bi awọn ti a kà ninu wọn, nwọn jẹ́ ọkẹ meji o le ẹdẹgbẹta.
Awọn ọmọ Juda, ni Eri ati Onani: ati Eri ati Onani kú ni ilẹ Kenaani.
Ati awọn ọmọ Juda gẹgẹ bi idile wọn; ti Ṣela, idile Ṣela: ti Peresi, idile Peresi: ti Sera, idile Sera.
Awọn ọmọ Peresi; ti Hesroni, idile Hesroni: ti Hamulu, idile Hamulu.
Wọnyi ni idile Juda gẹgẹ bi awọn ti a kà ninu wọn, nwọn jẹ́ ẹgba mejidilogoji o le ẹdẹgbẹta.
Awọn ọmọ Issakari gẹgẹ bi idile wọn: ti Tola, idile Tola: ti Pufa, idile Pufa:
Ti Jaṣubu, idile Jaṣubu: ti Ṣimroni, idile Ṣimroni.
Wọnyi ni idile Issakari gẹgẹ bi awọn ti a kà ninu wọn, nwọn jẹ́ ẹgba mejilelọgbọ̀n o le ọdunrun.
Awọn ọmọ Sebuluni gẹgẹ bi idile wọn: ti Seredi, idile Seredi: ti Eloni, idile Eloni: ti Jaleeli, idile Jaleeli.
Wọnyi ni idile awọn ọmọ Sebuluni gẹgẹ bi awọn ti a kà ninu wọn, nwọn jẹ́ ọkẹ mẹta o le ẹdẹgbẹta.
Awọn ọmọ Josefu gẹgẹ bi idile wọn: Manasse ati Efraimu.
Awọn ọmọ Manasse: ti Makiri, idile Makiri: Makiri si bi Gileadi: ti Gileadi, idile awọn ọmọ Gileadi.
Wọnyi li awọn ọmọ Gileadi: ti Ieseri, idile Ieseri: ti Heleki, idile Heleki:
Ati ti Asrieli, idile Asrieli: ati ti Ṣekemu, idile Ṣekemu:
Ati Ṣemida, idile awọn ọmọ Ṣemida: ati ti Heferi, idile awọn ọmọ Heferi.
Selofehadi ọmọ Heferi kò si lí ọmọkunrin, bikọse ọmọbinrin: orukọ awọn ọmọbinrin Selofehadi a ma jẹ Mala, ati Noa, ati Hogla, Milka, ati Tirsa.
Wọnyi ni idile Manasse, ati awọn ti a kà ninu wọn jẹ́ ẹgba mẹrindilọgbọ̀n o le ẹdẹgbẹrin.
Wọnyi li awọn ọmọ Efraimu gẹgẹ bi idile wọn: ti Ṣutela, idile awọn ọmọ Ṣutela: ti Bekeri, idile awọn ọmọ Bekeri: ti Tahani, idile awọn ọmọ Tahani.
Wọnyi li awọn ọmọ Ṣutela: ti Erani, idile awọn ọmọ Erani.
Wọnyi ni idile awọn ọmọ Efraimu gẹgẹ bi awọn ti a kà ninu wọn, nwọn jẹ́ ẹgba mẹrindilogun o le ẹdẹgbẹta. Wọnyi li awọn ọmọ Josefu gẹgẹ bi idile wọn.
Awọn ọmọ Benjamini gẹgẹ bi idile wọn: ti Bela, idile awọn ọmọ Bela: ti Aṣbeli, idile awọn ọmọ Aṣbeli: ti Ahiramu, idile awọn ọmọ Ahiramu.
Ti Ṣefamu, idile awọn ọmọ Ṣufamu: ti Hufamu, idile awọn ọmọ Hufamu.
Awọn ọmọ Bela si ni Ardi ati Naamani: ti Ardi, idile awọn ọmọ Ardi: ati ti Naamani, idile awọn ọmọ Naamani.
Wọnyi li awọn ọmọ Benjamini gẹgẹ bi idile wọn: ati awọn ti a kà ninu wọn jẹ́ ẹgba mejilelogun o le ẹgbẹjọ.
Wọnyi li awọn ọmọ Dani gẹgẹ bi idile wọn: ti Ṣuhamu, idile awọn ọmọ Ṣuhamu. Wọnyi ni idile Dani gẹgẹ bi idile wọn.
Gbogbo idile awọn ọmọ Ṣuhamu, gẹgẹ bi awọn ti a kà ninu wọn, nwọn jẹ́ ẹgba mejilelọgbọ̀n o le irinwo.
Ti awọn ọmọ Aṣeri gẹgẹ bi idile wọn: ti Imna, idile awọn ọmọ Imna: ti Iṣfi, idile awọn ọmọ Iṣfi: ti Beria, idile awọn ọmọ Beria.
Ti awọn ọmọ Beria: ti Heberi, idile awọn ọmọ Heberi: ti Malkieli, idile awọn ọmọ Malkieli.
Orukọ ọmọ Aṣeri obinrin a si ma jẹ́ Sera.
Wọnyi ni idile awọn ọmọ Aṣeri gẹgẹ bi awọn ti a kà ninu wọn; nwọn jẹ́ ẹgba mẹrindilọgbọ̀n o le egbeje.
Ti awọn ọmọ Naftali gẹgẹ bi idile wọn: ti Jaseeli, idile awọn ọmọ Jaseeli: ti Guni, idile awọn ọmọ Guni:
Ti Jeseri, idile awọn ọmọ Jeseri: ti Ṣillemu, idile awọn ọmọ Ṣillemu.
Wọnyi ni idile ti Naftali gẹgẹ bi idile wọn: awọn ti a si kà ninu wọn jẹ́ ẹgba mejilelogun o le egbeje.
Wọnyi li a kà ninu awọn ọmọ Israeli, ọgbọ̀n ọkẹ, o le ẹgbẹsan o din ãdọrin.