Num 26:1-51

Num 26:1-51 Bibeli Mimọ (YBCV)

O SI ṣe lẹhin àrun na, ni OLUWA sọ fun Mose ati fun Eleasari alufa ọmọ Aaroni pe, Kà iye gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gẹgẹ bi ile awọn baba wọn, gbogbo awọn ti o le lọ si ogun ni Israeli. Mose ati Eleasari alufa si sọ fun wọn ni pẹtẹlẹ̀ Moabu, lẹba Jordani leti Jeriko pe, Ẹ kà iye awọn enia na, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose, ati fun awọn ọmọ Israeli, ti o ti ilẹ Egipti jade wá. Reubeni, akọ́bi Israeli: awọn ọmọ Reubeni; Hanoki, lati ọdọ ẹniti idile awọn ọmọ Hanoki ti wá: ti Pallu, idile awọn ọmọ Pallu: Ti Hesroni, idile awọn ọmọ Hesroni: ti Karmi, idile awọn ọmọ Karmi. Wọnyi ni idile awọn ọmọ Reubeni: awọn ti a si kà ninu wọn jẹ́ ẹgba mọkanlelogun o le ẹgbẹsan o din ãdọrin. Ati awọn ọmọ Pallu; Eliabu. Ati awọn ọmọ Eliabu; Nemueli, ati Datani, ati Abiramu. Eyi ni Datani ati Abiramu na, ti nwọn lí okiki ninu ijọ, ti nwọn bá Mose ati Aaroni jà ninu ẹgbẹ Kora, nigbati nwọn bá OLUWA jà. Ti ilẹ si là ẹnu rẹ̀, ti o si gbe wọn mì pọ̀ pẹlu Kora, nigbati ẹgbẹ na fi kú, nigbati iná fi run awọn ãdọtalerugba ọkunrin, ti nwọn si di àmi kan. Ṣugbọn awọn ọmọ Kora kò kú. Awọn ọmọ Simeoni bi idile wọn: ti Nemueli, idile Nemueli: ti Jamini, idile Jamini: ti Jakini, idile Jakini: Ti Sera, idile Sera: ti Ṣaulu, idile Ṣaulu. Wọnyi ni idile awọn ọmọ Simeoni, ẹgba mọkanla o le igba. Awọn ọmọ Gadi bi idile wọn: ti Sefoni, idile Sefoni: ti Haggi, idile Haggi: ti Ṣuni, idile Ṣuni: Ti Osni, idile Osni: ti Eri, idile Eri: Ti Arodu, idile Arodu: ti Areli, idile Areli. Wọnyi ni idile awọn ọmọ Gadi gẹgẹ bi awọn ti a kà ninu wọn, nwọn jẹ́ ọkẹ meji o le ẹdẹgbẹta. Awọn ọmọ Juda, ni Eri ati Onani: ati Eri ati Onani kú ni ilẹ Kenaani. Ati awọn ọmọ Juda gẹgẹ bi idile wọn; ti Ṣela, idile Ṣela: ti Peresi, idile Peresi: ti Sera, idile Sera. Awọn ọmọ Peresi; ti Hesroni, idile Hesroni: ti Hamulu, idile Hamulu. Wọnyi ni idile Juda gẹgẹ bi awọn ti a kà ninu wọn, nwọn jẹ́ ẹgba mejidilogoji o le ẹdẹgbẹta. Awọn ọmọ Issakari gẹgẹ bi idile wọn: ti Tola, idile Tola: ti Pufa, idile Pufa: Ti Jaṣubu, idile Jaṣubu: ti Ṣimroni, idile Ṣimroni. Wọnyi ni idile Issakari gẹgẹ bi awọn ti a kà ninu wọn, nwọn jẹ́ ẹgba mejilelọgbọ̀n o le ọdunrun. Awọn ọmọ Sebuluni gẹgẹ bi idile wọn: ti Seredi, idile Seredi: ti Eloni, idile Eloni: ti Jaleeli, idile Jaleeli. Wọnyi ni idile awọn ọmọ Sebuluni gẹgẹ bi awọn ti a kà ninu wọn, nwọn jẹ́ ọkẹ mẹta o le ẹdẹgbẹta. Awọn ọmọ Josefu gẹgẹ bi idile wọn: Manasse ati Efraimu. Awọn ọmọ Manasse: ti Makiri, idile Makiri: Makiri si bi Gileadi: ti Gileadi, idile awọn ọmọ Gileadi. Wọnyi li awọn ọmọ Gileadi: ti Ieseri, idile Ieseri: ti Heleki, idile Heleki: Ati ti Asrieli, idile Asrieli: ati ti Ṣekemu, idile Ṣekemu: Ati Ṣemida, idile awọn ọmọ Ṣemida: ati ti Heferi, idile awọn ọmọ Heferi. Selofehadi ọmọ Heferi kò si lí ọmọkunrin, bikọse ọmọbinrin: orukọ awọn ọmọbinrin Selofehadi a ma jẹ Mala, ati Noa, ati Hogla, Milka, ati Tirsa. Wọnyi ni idile Manasse, ati awọn ti a kà ninu wọn jẹ́ ẹgba mẹrindilọgbọ̀n o le ẹdẹgbẹrin. Wọnyi li awọn ọmọ Efraimu gẹgẹ bi idile wọn: ti Ṣutela, idile awọn ọmọ Ṣutela: ti Bekeri, idile awọn ọmọ Bekeri: ti Tahani, idile awọn ọmọ Tahani. Wọnyi li awọn ọmọ Ṣutela: ti Erani, idile awọn ọmọ Erani. Wọnyi ni idile awọn ọmọ Efraimu gẹgẹ bi awọn ti a kà ninu wọn, nwọn jẹ́ ẹgba mẹrindilogun o le ẹdẹgbẹta. Wọnyi li awọn ọmọ Josefu gẹgẹ bi idile wọn. Awọn ọmọ Benjamini gẹgẹ bi idile wọn: ti Bela, idile awọn ọmọ Bela: ti Aṣbeli, idile awọn ọmọ Aṣbeli: ti Ahiramu, idile awọn ọmọ Ahiramu. Ti Ṣefamu, idile awọn ọmọ Ṣufamu: ti Hufamu, idile awọn ọmọ Hufamu. Awọn ọmọ Bela si ni Ardi ati Naamani: ti Ardi, idile awọn ọmọ Ardi: ati ti Naamani, idile awọn ọmọ Naamani. Wọnyi li awọn ọmọ Benjamini gẹgẹ bi idile wọn: ati awọn ti a kà ninu wọn jẹ́ ẹgba mejilelogun o le ẹgbẹjọ. Wọnyi li awọn ọmọ Dani gẹgẹ bi idile wọn: ti Ṣuhamu, idile awọn ọmọ Ṣuhamu. Wọnyi ni idile Dani gẹgẹ bi idile wọn. Gbogbo idile awọn ọmọ Ṣuhamu, gẹgẹ bi awọn ti a kà ninu wọn, nwọn jẹ́ ẹgba mejilelọgbọ̀n o le irinwo. Ti awọn ọmọ Aṣeri gẹgẹ bi idile wọn: ti Imna, idile awọn ọmọ Imna: ti Iṣfi, idile awọn ọmọ Iṣfi: ti Beria, idile awọn ọmọ Beria. Ti awọn ọmọ Beria: ti Heberi, idile awọn ọmọ Heberi: ti Malkieli, idile awọn ọmọ Malkieli. Orukọ ọmọ Aṣeri obinrin a si ma jẹ́ Sera. Wọnyi ni idile awọn ọmọ Aṣeri gẹgẹ bi awọn ti a kà ninu wọn; nwọn jẹ́ ẹgba mẹrindilọgbọ̀n o le egbeje. Ti awọn ọmọ Naftali gẹgẹ bi idile wọn: ti Jaseeli, idile awọn ọmọ Jaseeli: ti Guni, idile awọn ọmọ Guni: Ti Jeseri, idile awọn ọmọ Jeseri: ti Ṣillemu, idile awọn ọmọ Ṣillemu. Wọnyi ni idile ti Naftali gẹgẹ bi idile wọn: awọn ti a si kà ninu wọn jẹ́ ẹgba mejilelogun o le egbeje. Wọnyi li a kà ninu awọn ọmọ Israeli, ọgbọ̀n ọkẹ, o le ẹgbẹsan o din ãdọrin.

Num 26:1-51 Yoruba Bible (YCE)

Lẹ́yìn àjàkálẹ̀ àrùn náà, OLUWA sọ fún Mose ati Eleasari alufaa ọmọ Aaroni pé, “Ẹ ka iye àwọn ọmọ Israẹli, àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún tabi jù bẹ́ẹ̀ lọ, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé.” Mose ati Eleasari alufaa sì pe àwọn eniyan náà jọ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu, lẹ́bàá odò Jọdani, létí Jẹriko, wọ́n sọ fún wọn pé, “Ẹ ka iye àwọn eniyan náà láti ẹni ogún ọdún lọ sókè,” gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose. Àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n jáde láti ilẹ̀ Ijipti nìwọ̀nyí: Reubẹni ni àkọ́bí Israẹli. Àwọn ọmọ Reubẹni ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Hanoku, ìdílé Palu, ìdílé Hesironi, ìdílé Karimi. Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Reubẹni jẹ́ ẹgbaa mọkanlelogun ó lé ẹgbẹsan ó dín aadọrin (43,730). Palu bí Eliabu, Eliabu bí Nemueli, Datani ati Abiramu. Datani ati Abiramu yìí ni wọ́n jẹ́ olókìkí eniyan láàrin àwọn ọmọ Israẹli. Àwọn ni wọ́n bá Mose ati Aaroni ṣe gbolohun asọ̀ nígbà tí Kora dìtẹ̀, tí wọ́n tako OLUWA. Nígbà náà ni ilẹ̀ lanu, tí ó gbé wọn mì pẹlu Kora, wọ́n sì kú, òun ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. Nígbà náà ni iná jó àwọn aadọta leerugba (250) ọkunrin tí wọn tẹ̀lé Kora, wọ́n sì di ohun ìkìlọ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli. Ṣugbọn àwọn ọmọ Kora kò kú. Àwọn ọmọ Simeoni ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Nemueli, ìdílé Jamini, ati ìdílé Jakini; ìdílé Sera ati ti Ṣaulu. Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Simeoni jẹ́ ẹgbaa mọkanla ó lé igba (22,200). Àwọn ọmọ Gadi ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Sefoni, ìdílé Hagi, ati ìdílé Ṣuni; ìdílé Osini, ati ìdílé Eri; ìdílé Arodu ati ìdílé Areli. Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Gadi jẹ́ ọ̀kẹ́ meji ó lé ẹẹdẹgbẹta (40,500). Àwọn ọmọ Juda ni Eri ati Onani. Eri ati Onani kú ní ilẹ̀ Kenaani. Àwọn ọmọ Juda ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Ṣela, ìdílé Peresi, ati ìdílé Sera. Àwọn ọmọ Peresi nìwọ̀nyí: ìdílé Hesironi ati ìdílé Hamuli. Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Juda jẹ́ ẹgbaa mejidinlogoji ó lé ẹẹdẹgbẹta (76,500). Àwọn ọmọ Isakari ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Tola, ìdílé Pua; ìdílé Jaṣubu ati ìdílé Ṣimironi. Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Isakari jẹ́ ẹgbaa mejilelọgbọn ó lé ọọdunrun (64,300). Àwọn ọmọ Sebuluni ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Seredi, ìdílé Eloni ati ìdílé Jaleeli. Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Sebuluni jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹta ó lé ẹẹdẹgbẹta (60,500). Àwọn ọmọ Josẹfu ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: Manase ati Efuraimu. Àwọn ọmọ Manase ni: ìdílé Makiri, Makiri bí Gileadi. Àwọn ọmọ Gileadi nìwọ̀nyí: ìdílé Ieseri, ìdílé Heleki; ìdílé Asirieli, ìdílé Ṣekemu; ìdílé Ṣemida, ìdílé Heferi. Selofehadi ọmọ Heferi kò bí ọmọkunrin kankan, àfi ọmọbinrin. Orúkọ àwọn ọmọbinrin Selofehadi ni Mahila, Noa, Hogila, Milika ati Tirisa. Gbogbo àwọn tí a kà ninu ìdílé Manase jẹ́ ẹgbaa mẹrindinlọgbọn ó lé ẹẹdẹgbẹrin (52,700). Àwọn ọmọ Efuraimu ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Ṣutela, ìdílé Bekeri ati ìdílé Tahani. Àwọn ọmọ Ṣutela nìwọ̀nyí, ìdílé Erani. Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Efuraimu jẹ́ ẹgbaa mẹrindinlogun ó lé ẹẹdẹgbẹta (32,500). Àwọn ni ọmọ Josẹfu ní ìdílé-ìdílé. Àwọn ọmọ Bẹnjamini ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Bela, ìdílé Aṣibeli, ìdílé Ahiramu; ìdílé Ṣefufamu ati ìdílé Hufamu. Àwọn ọmọ Bela nìwọ̀nyí: ìdílé Aridi ati ìdílé Naamani. Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Bẹnjamini jẹ́ ẹgbaa mejilelogun ó lé ẹgbẹjọ (45,600). Àwọn ọmọ Dani ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Ṣuhamu. Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Dani jẹ́ ẹgbaa mejilelọgbọn ó lé irinwo (64,400). Àwọn ọmọ Aṣeri ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Imina, ìdílé Iṣifi ati ìdílé Beria. Àwọn ọmọ Beria ni: ìdílé Heberi ati ìdílé Malikieli. Orúkọ ọmọ Aṣeri obinrin sì ni Sera. Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Aṣeri jẹ́ ẹgbaa mẹrindinlọgbọn ó lé egbeje (53,400). Àwọn ọmọ Nafutali ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Jahiseeli, ìdílé Guni, ìdílé Jeseri ati ìdílé Ṣilemu. Gbogbo àwọn tí a kà ninu ẹ̀yà Nafutali jẹ́ ẹgbaa mejilelogun ó lé egbeje (45,400). Gbogbo wọn ní àpapọ̀ jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó lé ẹgbẹsan ó dín aadọrin (601,730).

Num 26:1-51 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Lẹ́yìn àjàkálẹ̀-ààrùn OLúWA sọ fún Mose àti Eleasari ọmọ Aaroni, àlùfáà pé “Ka iye gbogbo àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọ́n; láti ẹni ogun (20) ọdún àti jù bẹ́ẹ̀ lọ tí ó lè jà lójú ogun ní Israẹli.” Lórí pẹ̀tẹ́lẹ̀ ti Moabu pẹ̀lú Jordani tí ó kọjá Jeriko, Mose àti Eleasari àlùfáà sọ̀rọ̀ pẹ̀lú wọn ó wí pé, “Ka iye àwọn ọkùnrin tí ó jẹ́ ọmọ-ogun (20) ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, gẹ́gẹ́ bí OLúWA ti pàṣẹ fún Mose.” Èyí ni àwọn ọmọ Israẹli tí ó jáde láti Ejibiti wá: Àwọn ọmọ Reubeni, àkọ́bí ọmọkùnrin Israẹli, láti ẹni ti ìdílé Hanoku, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ìdílé Hanoku ti jáde wá; Láti ìdílé Pallu, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ìdílé àwọn ọmọ Pallu ti jáde wá; ti Hesroni, ìdílé àwọn ọmọ Hesroni; ti Karmi, ìdílé àwọn ọmọ Karmi. Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Reubeni; àwọn tí a sì kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá-mọ́kànlélógún ó-lé-ẹgbẹ̀sán ó-dínàádọ́rin (43,730). Àwọn ọmọkùnrin Pallu ni Eliabu, àwọn ọmọkùnrin Elifelehu ni Nemueli àti Eliabu, Datani àti Abiramu. Èyí ni Datani àti Abiramu náà tí wọ́n ní òkìkí nínú ìjọ tí ó jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ sí Mose àti Aaroni tí ó sì wà lára àwọn ẹgbẹ́ Kora nígbà tí wọ́n bá OLúWA jà. Ilẹ̀ sì la ẹnu rẹ̀, ó sì gbé wọn mì pọ̀ pẹ̀lú Kora, nígbà tí ẹgbẹ́ rẹ̀ kú níbi tí iná ti run àwọn àádọ́tà-lé-nígba ọkùnrin (250). Tí wọ́n sì di ààmì ìkìlọ̀. Àwọn ọmọ Kora, bí ó ti wù kí ó rí, wọn kò kú. Àwọn ọmọ ìran Simeoni bí ìdílé wọn: ti Nemueli, ìdílé Nemueli; ti Jamini, ìdílé Jamini; ti Jakini, ìdílé Jakini; ti Sera, ìdílé Sera; tí Saulu, ìdílé Saulu. Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Simeoni, ẹgbàá-mọ́kànlá ó-lé-igba. (22,200) ọkùnrin. Àwọn ọmọ Gadi bí ìdílé wọn: ti Sefoni, ìdílé Sefoni; ti Haggi, ìdílé Haggi; ti Ṣuni, ìdílé Ṣuni; ti Osni, ìdílé Osni; ti Eri, ìdílé Eri; ti Arodi, ìdílé Arodi; ti Areli, ìdílé Areli. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Gadi tí iye wọn sì jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (40,500). Àwọn ọmọ Juda ni Eri àti Onani, ṣùgbọ́n Eri àti Onani kú ní ilẹ̀ Kenaani. Àti àwọn ọmọ Juda gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn: ti Ṣela, ìdílé Ṣela; ti Peresi, ìdílé Peresi; ti Sera, ìdílé Sera. Àwọn ọmọ Peresi: ti Hesroni, ìdílé Hesroni; ti Hamulu, ìdílé Hamulu. Wọ̀nyí ni ìdílé Juda; gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbàá-méjì-dínlógójì ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta. (76,500). Àwọn ọmọ Isakari gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn: ti Tola, ìdílé Tola; ti Pufa, ìdílé Pufa; ti Jaṣubu, ìdílé Jaṣubu; ti Ṣimroni, ìdílé Ṣimroni. Wọ̀nyí ni ìdílé Isakari gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbàá-méjìlélọ́gbọ̀n ó-lé-ọ̀ọ́dúnrún (64,300). Àwọn ọmọ Sebuluni gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn: ti Seredi, ìdílé Seredi; ti Eloni, ìdílé Eloni; ti Jaleeli, ìdílé Jaleeli. Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Sebuluni gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn tí iye wọn sì jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́ta ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (60,500). Àwọn ọmọ Josẹfu gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn; Manase àti Efraimu: Àwọn ọmọ Manase: ti Makiri, ìdílé Makiri (Makiri sì bí Gileadi); ti Gileadi, ìdílé àwọn ọmọ Gileadi. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Gileadi: ti Ieseri, ìdílé Ieseri; ti Heleki, ìdílé Heleki àti ti Asrieli, ìdílé Asrieli; àti ti Ṣekemu, ìdílé Ṣekemu; àti Ṣemida, ìdílé àwọn ọmọ Ṣemida; àti ti Heferi, ìdílé àwọn ọmọ Heferi. (Ṣelofehadi ọmọ Heferi kò sì ni ọmọkùnrin, bí kò ṣe ọmọbìnrin; orúkọ àwọn ọmọbìnrin ni Mahila, Noa, àti Hogla, Milka àti Tirsa). Wọ̀nyí ni ìdílé Manase tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbàá-mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (52,700). Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Efraimu gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn: láti ọ̀dọ̀ Ṣutelahi, ìdílé àwọn ọmọ Ṣutelahi; ti Bekeri, ìdílé àwọn ọmọ Bekeri; ti Tahani, ìdílé àwọn ọmọ Tahani. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Ṣutelahi: ti Erani, ìdílé àwọn ọmọ Erani; Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Efraimu, àwọn tí a kà nínú wọn sì jẹ́ ẹgbàá-mẹ́rìn-dínlógún ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (32,500). Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Josẹfu gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn. Àwọn ọmọ Benjamini gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn nìyìí: tí Bela, ìdílé àwọn ọmọ Bela; ti Aṣbeli, ìdílé àwọn ọmọ Aṣbeli; ti Ahiramu, ìdílé àwọn ọmọ Ahiramu; ti Ṣufamu, ìdílé àwọn ọmọ Ṣufamu; ti Hufamu, ìdílé àwọn ọmọ Hufamu. Àwọn ọmọ Bela ní ipasẹ̀ Ardi àti Naamani nìyìí: ti Ardi, ìdílé àwọn ọmọ Ardi; ti Naamani, ìdílé àwọn ọmọ Naamani. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Benjamini; gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn; àti àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá-méjìlélógún ó-lé-ẹgbẹ̀jọ (45,600). Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Dani gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn: ti Ṣuhamu, ìdílé àwọn ọmọ Ṣuhamu Wọ̀nyí ni ìdílé Dani gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn: Gbogbo ìdílé àwọn ọmọ Ṣuhamu, gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá-méjìlélọ́gbọ̀n ó-lé-irínwó (64,400). Ti àwọn ọmọ Aṣeri gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn: ti Imina, ìdílé àwọn ọmọ Imina; ti Iṣfi, ìdílé àwọn ọmọ Iṣfi; ti Beriah, ìdílé àwọn ọmọ Berii; Ti àwọn ọmọ Beriah: ti Heberi, ìdílé àwọn ọmọ Heberi; ti Malkieli, ìdílé àwọn ọmọ Malkieli. (Orúkọ ọmọ Aṣeri obìnrin nì jẹ́ Sera.) Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Aṣeri gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá-mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ó-lé-egbèje (53,400). Ti àwọn ọmọ Naftali gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn: ti Jasieli, ìdílé àwọn ọmọ Jaseeli: ti Guni, ìdílé àwọn ọmọ Guni; ti Jeseri, ìdílé àwọn ọmọ Jeṣeri; ti Ṣillemu, ìdílé àwọn ọmọ Ṣillemu. Wọ̀nyí ni ìdílé ti Naftali gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn, àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá-méjìlélógún ó-lé-egbèje (45,400). Àpapọ̀ iye tí a kà nínú àwọn ọmọ Israẹli jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó-lé-ẹgbẹ̀sán ó-dínàádọ́rin (601,730).