Num 25:1-3

Num 25:1-3 YBCV

ISRAELI si joko ni Ṣittimu, awọn enia na si bẹ̀rẹsi iṣe panṣaga pẹlu awọn ọmọbinrin Moabu: Nwọn si pe awọn enia na si ẹbọ oriṣa wọn; awọn enia na si jẹ, nwọn si tẹriba fun oriṣa wọn. Israeli si dà ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ Baali-peoru: ibinu OLUWA si rú si Israeli.