NỌMBA 25:1-3

NỌMBA 25:1-3 YCE

Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli pàgọ́ sí àfonífojì Ṣitimu, àwọn ọkunrin wọn ń bá àwọn ọmọbinrin Moabu tí wọ́n wà níbẹ̀ ṣe àgbèrè. Àwọn obinrin wọnyi a sì máa pè wọ́n lọ síbi àsè ìbọ̀rìṣà. Wọn a máa jẹ oúnjẹ wọn, wọn a sì ma bá wọn bọ oriṣa wọn. Báyìí ni àwọn ọmọ Israẹli ṣe da ara wọn pọ̀ mọ́ oriṣa Baali tí ó wà ní Peori, ibinu OLUWA sì ru sí wọn.