Mak 5:30-34

Mak 5:30-34 YBCV

Lọgan Jesu si ti mọ̀ ninu ara rẹ̀ pe, aṣẹ ti ara on jade, o yipada larin ọpọ enia, o si wipe, Tali o fi ọwọ́ kàn mi li aṣọ? Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wi fun u pe, Iwọ ri bi ijọ enia ti nhá ọ li àye, iwọ si nwipe, Tali o fi ọwọ́ tọ́ mi? O si wò yiká lati ri ẹniti o ṣe nkan yi. Ṣugbọn obinrin na ni ibẹ̀ru ati iwarìri, bi o ti mọ̀ ohun ti a ṣe lara on, o wá, o si wolẹ niwaju rẹ̀, o si sọ gbogbo otitọ fun u. O si wi fun u pe, Ọmọbinrin, igbagbọ́ rẹ mu ọ larada; mã lọ li alafia, ki iwọ ki o si sàn ninu arun rẹ.

Àwọn fídíò fún Mak 5:30-34