MAKU 5:30-34

MAKU 5:30-34 YCE

Lójú kan náà Jesu mọ̀ ninu ara rẹ̀ pé agbára ìwòsàn jáde lára òun. Ó bá yipada sí àwọn eniyan, ó bèèrè pé, “Ta ni fọwọ́ kàn mí láṣọ?” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “O rí i bí àwọn eniyan ti ń fún ọ lọ́tùn-ún lósì, o tún ń bèèrè pé ta ni fọwọ́ kàn ọ́?” Ṣugbọn Jesu ń wò yíká láti rí ẹni tí ó fọwọ́ kan aṣọ rẹ̀. Obinrin náà mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ lára òun, ó bá yọ jáde. Ẹ̀rù bà á, ó ń gbọ̀n, ó bá wá kúnlẹ̀ níwájú Jesu, ó sọ gbogbo òtítọ́ ọ̀rọ̀ náà fún un. Jesu wí fún un pé, “Arabinrin, igbagbọ rẹ ti mú ọ lára dá. Máa lọ ní alaafia, o kò ní gbúròó àìsàn náà mọ́.”

Àwọn fídíò fún MAKU 5:30-34