Mat 13:4-9

Mat 13:4-9 YBCV

Bi o si ti nfún u, diẹ bọ́ si ẹba-ọ̀na, awọn ẹiyẹ si wá, nwọn si ṣà a jẹ. Diẹ si bọ sori ilẹ apata, nibiti kò li erupẹ̀ pipọ; nwọn si sọ jade lọgan, nitoriti nwọn ko ni ijinlẹ; Nigbati õrùn si goke, nwọn jona: nitoriti nwọn kò ni gbongbo, nwọn si gbẹ. Diẹ si bọ́ sãrin ẹ̀gún; nigbati ẹ̀gún si dàgba soke, o fun wọn pa. Ṣugbọn omiran bọ́ si ilẹ rere, o si so eso, omiran ọgọrọrun, omiran ọgọtọta, omiran ọgbọgbọ̀n. Ẹniti o ba li etí, ki o gbọ́.

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ