Mat 13:4-9
Mat 13:4-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bi o si ti nfún u, diẹ bọ́ si ẹba-ọ̀na, awọn ẹiyẹ si wá, nwọn si ṣà a jẹ. Diẹ si bọ sori ilẹ apata, nibiti kò li erupẹ̀ pipọ; nwọn si sọ jade lọgan, nitoriti nwọn ko ni ijinlẹ; Nigbati õrùn si goke, nwọn jona: nitoriti nwọn kò ni gbongbo, nwọn si gbẹ. Diẹ si bọ́ sãrin ẹ̀gún; nigbati ẹ̀gún si dàgba soke, o fun wọn pa. Ṣugbọn omiran bọ́ si ilẹ rere, o si so eso, omiran ọgọrọrun, omiran ọgọtọta, omiran ọgbọgbọ̀n. Ẹniti o ba li etí, ki o gbọ́.
Mat 13:4-9 Yoruba Bible (YCE)
Bí ó ti ń fúnrúgbìn, àwọn irúgbìn kan bọ́ sẹ́bàá ọ̀nà. Àwọn ẹyẹ bá wá ṣà á jẹ. Àwọn irúgbìn mìíràn bọ́ sórí ilẹ̀ olókùúta tí kò ní erùpẹ̀ pupọ. Lọ́gán ó yọ sókè, nítorí kò ní erùpẹ̀ tí ó jinlẹ̀. Ṣugbọn nígbà tí oòrùn mú, ó jó o pa, nítorí kò ní gbòǹgbò tí ó jinlẹ̀; ó bá rọ. Àwọn irúgbìn mìíràn bọ́ sáàrin igi ẹlẹ́gùn-ún. Nígbà tí wọ́n yọ, ẹ̀gún fún wọn pa. Ṣugbọn àwọn irúgbìn mìíràn bọ́ sórí ilẹ̀ rere, wọ́n sì ń so èso, àwọn mìíràn ń so ọgọọgọrun-un, àwọn mìíràn ọgọọgọta, àwọn mìíràn, ọgbọọgbọn. “Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ràn, kí ó gbọ́!”
Mat 13:4-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bí ó sì ti gbin irúgbìn náà, díẹ̀ bọ́ sí ẹ̀bá ọ̀nà, àwọn ẹyẹ sì wá, wọ́n sì jẹ ẹ́. Díẹ̀ bọ́ sórí ilẹ̀ orí àpáta, níbi ti kò sí erùpẹ̀ púpọ̀. Àwọn irúgbìn náà sì dàgbàsókè kíákíá, nítorí erùpẹ̀ kò pọ̀ lórí wọn. Ṣùgbọ́n nígbà tí oòrùn gòkè, oòrùn gbígbóná jó wọn, gbogbo wọn sì rọ, wọ́n kú nítorí wọn kò ni gbòǹgbò. Àwọn irúgbìn mìíràn bọ́ sí àárín ẹ̀gún, ẹ̀gún sì dàgbà, ó sì fún wọn pa. Ṣùgbọ́n díẹ̀ tó bọ́ sórí ilẹ̀ rere, ó sì so èso, òmíràn ọgọ́ọ̀rún, òmíràn ọgọ́tọ̀ọ̀ta, òmíràn ọgbọọgbọ̀n, ni ìlọ́po èyí ti ó gbìn. Ẹni tí ó bá létí, kí ó gbọ́.”