O si ṣe, nigbati Jesu pari aṣẹ rẹ̀ tan fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ mejejila, o ti ibẹ̀ rekọja lati ma kọni, ati lati ma wasu ni ilu wọn gbogbo. Nigbati Johanu gburo iṣẹ Kristi ninu tubu, o rán awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ meji, O si wipe, Iwọ li ẹniti mbọ̀, tabi ki a mã reti ẹlomiran? Jesu si dahùn o wi fun wọn pe, Ẹ pada lọ, ẹ si sọ ohun wọnyi ti ẹnyin gbọ́, ti ẹ si ri fun Johanu: Awọn afọju nriran, awọn amukun si nrìn, a nwẹ̀ awọn adẹtẹ̀ mọ́, awọn aditi ngbọràn, a njí awọn okú dide, a si nwasu ihinrere fun awọn òtoṣi. Alabukun-fun si li ẹnikẹni ti kì yio ri ohun ikọsẹ ninu mi. Nigbati nwọn si lọ, Jesu bẹrẹ si sọ fun awọn enia niti Johanu pe, Kili ẹnyin jade lọ iwò ni ijù? Ifefe ti afẹfẹ nmì? Ani kili ẹnyin jade lọ iwò? Ọkunrin ti a wọ̀ li aṣọ fẹlẹfẹlẹ? wò o, awọn ẹniti nwọ̀ aṣọ fẹlẹfẹlẹ mbẹ li afin ọba. Ani kili ẹnyin jade lọ iṣe? lati lọ iwò wolĩ? Lõtọ ni mo wi fun nyin, o si jù wolĩ lọ. Nitori eyiyi li ẹniti a ti kọwe nitori rẹ̀ pe, Wò o, mo rán onṣẹ mi siwaju rẹ, ẹniti yio tún ọ̀na rẹ ṣe niwaju rẹ.
Kà Mat 11
Feti si Mat 11
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Mat 11:1-10
5 Days
God is awakening His Church, and we need to see the big picture. When times get tough, we will be tempted to quit. It is not, however, time to quit. Join us as we learn how to read the times we are in, as well as gain strategies on how to stand and advance the Kingdom of God.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò