Mat 11:1-10

Mat 11:1-10 Yoruba Bible (YCE)

Lẹ́yìn tí Jesu ti fi gbogbo ìlànà wọnyi lélẹ̀ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mejila tán, ó kúrò níbẹ̀ lọ sí àwọn ìlú wọn, ó ń kọ àwọn eniyan ó sì ń waasu. Johanu gbọ́ ninu ẹ̀wọ̀n nípa iṣẹ́ tí Jesu ń ṣe. Ó bá rán àwọn kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kí wọ́n lọ bi í pé, “Ṣé ìwọ ni ẹni tí ó ń bọ̀ ni, tabi kí á máa retí ẹlòmíràn?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ lọ ròyìn ohun tí ẹ ti gbọ́ ati ohun tí ẹ ti rí fún Johanu. Ẹ sọ fún un pé, àwọn afọ́jú ń ríran, àwọn arọ ń rìn, ara àwọn adẹ́tẹ̀ ń di mímọ́, àwọn adití ń gbọ́ràn, à ń jí àwọn òkú dìde, a sì ń waasu ìyìn rere fún àwọn talaka. Ẹni tí kò bá ṣiyèméjì nípa mi ṣe oríire!” Nígbà tí àwọn oníṣẹ́ Johanu pada lọ, Jesu bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún àwọn eniyan nípa Johanu pé, “Kí ni ẹ jáde lọ wò ní aṣálẹ̀? Ṣé koríko tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ síhìn-ín, sọ́hùn-ún? Rárá o! Kí wá ni ẹ jáde lọ wò? Ẹni tí ó wọ aṣọ iyebíye ni bí? Bí ẹ bá ń wá àwọn tí ó wọ aṣọ olówó iyebíye, ẹ lọ sí ààfin ọba! Ṣugbọn kí ni ẹ jáde lọ wò? Wolii ni bí? Bẹ́ẹ̀ ni. Mo sọ fun yín, ó tilẹ̀ ju wolii lọ. Òun ni àkọsílẹ̀ wà nípa rẹ̀ pé: ‘Wò ó! Mo rán oníṣẹ́ mi ṣiwaju rẹ òun ni yóo palẹ̀ mọ́ dè ọ́.’

Mat 11:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Lẹ́yìn ìgbà tí Jesu sì ti parí ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá, ó ti ibẹ̀ rékọjá láti máa kọ́ni àti láti máa wàásù ní àwọn ìlú Galili gbogbo. Nígbà tí Johanu gbọ́ ohun tí Kristi ṣe nínú ẹ̀wọ̀n, ó rán àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ṣe ìwọ ni ẹni tó ń bọ̀ wá tàbí kí a máa retí ẹlòmíràn?” Jesu dáhùn ó wí pé, “Ẹ padà lọ, ẹ sì sọ fún Johanu ohun tí ẹ̀yin gbọ́, àti èyí tí ẹ̀yin rí. Àwọn afọ́jú ń ríran, àwọn amúnkùn ún rìn, a ń wẹ àwọn adẹ́tẹ̀ mọ́ kúrò nínú ẹ̀tẹ̀ wọn, àwọn adití ń gbọ́rọ̀, a ń jí àwọn òkú dìde, a sì ń wàásù ìhìnrere fún àwọn òtòṣì. Alábùkún fún ni ẹni tí kò rí ohun ìkọ̀sẹ̀ nípa mi.” Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu ti lọ tán, Jesu bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún ọ̀pọ̀ ènìyàn nípa ti Johanu: “Kí ni ẹ̀yin jáde lọ wò ní aginjù? Ewéko tí afẹ́fẹ́ ń mi? Bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, kí ni ẹ̀yin lọ òde lọ í wò? Ọkùnrin tí a wọ̀ ni aṣọ dáradára? Rárá àwọn ti ó wọ aṣọ dáradára wà ní ààfin ọba. Àní kí ní ẹ jáde láti lọ wò? Wòlíì? Bẹ́ẹ̀ ni, mo wí fún yín, ó sì ju wòlíì lọ.” Èyí ni ẹni tí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: “ ‘Èmi yóò rán ìránṣẹ́ mi síwájú rẹ, ẹni tí yóò tún ọ̀nà rẹ ṣe níwájú rẹ.’