Ni ijọ kini ọ̀sẹ, ni kutukutu owurọ̀, nwọn wá si ibojì, nwọn nmu turari wá ti nwọn ti pèse silẹ, ati awọn miran kan pẹlu wọn. Nwọn si ba a, a ti yi okuta kuro li ẹnu ibojì. Nigbati nwọn wọ̀ inu rẹ̀, nwọn kò si ri okú Jesu Oluwa. O si ṣe, bi nwọn ti nṣe rọunrọ̀un kiri niha ibẹ̀, kiyesi i, awọn ọkunrin meji alaṣọ didan duro tì wọn: Nigbati ẹ̀ru mbà wọn, ti nwọn si dojubolẹ, awọn angẹli na bi wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi nwá alãye lãrin awọn okú? Ko si nihinyi, ṣugbọn o jinde: ẹ ranti bi o ti wi fun nyin nigbati o wà ni Galili, Pe, A ko le ṣaima fi Ọmọ-enia le awọn enia ẹlẹsẹ lọwọ, a o si kàn a mọ agbelebu, ni ijọ kẹta yio si jinde. Nwọn si ranti ọ̀rọ rẹ̀. Nwọn si pada ti ibojì wá, nwọn si ròhin gbogbo nkan wọnyi fun awọn mọkanla, ati fun gbogbo awọn iyokù. Maria Magdalene, ati Joanna, ati Maria, iya Jakọbu, ati awọn omiran pẹlu wọn si ni, ti nwọn ròhin nkan wọnyi fun awọn aposteli. Ọ̀rọ wọnyi si dabi isọkusọ loju wọn, nwọn kò si gbà wọn gbọ́.
Kà Luk 24
Feti si Luk 24
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Luk 24:1-11
7 Days
Nearly everyone agrees that this world is broken. But what if there’s a solution? This seven-day Easter plan begins with the unique experience of the thief on the cross and considers why the only real answer to brokenness is found in the execution of an innocent man: Jesus, the Son of God.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò