Luk 23:44-48

Luk 23:44-48 YBCV

O si to ìwọn wakati kẹfa ọjọ, òkunkun si ṣú bò gbogbo ilẹ titi o fi di wakati kẹsan ọjọ. Õrùn si ṣú õkun, aṣọ ikele ti tẹmpili si ya li agbedemeji. Nigbati Jesu si kigbe li ohùn rara, o ni, Baba, li ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹmí mi le: nigbati o si wi eyi tan, o jọwọ ẹmí rẹ̀ lọwọ. Nigbati balogun ọrún ri ohun ti o ṣe, o yìn Ọlọrun logo, wipe, Dajudaju olododo li ọkunrin yi. Gbogbo ijọ enia ti o pejọ si iran yi, nigbati nwọn nwò ohun ti nṣe, nwọn a lù ara wọn li õkan àiya, nwọn a si pada.

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ