Luk 2:16-21

Luk 2:16-21 YBCV

Nwọn si wá lọgan, nwọn si ri Maria, ati Josefu, ati ọmọ-ọwọ na, o dubulẹ ninu ibujẹ ẹran. Nigbati nwọn si ti ri i, nwọn sọ ohun ti a ti wi fun wọn nipa ti ọmọ yi. Ẹnu si yà gbogbo awọn ti o gbọ́ si nkan wọnyi, ti a ti wi fun wọn lati ọdọ awọn oluṣọ-agutan wá. Ṣugbọn Maria pa gbogbo nkan wọnyi mọ́, o nrò wọn ninu ọkàn rẹ̀. Awọn oluṣọ-agutan si pada lọ, nwọn nfi ogo fun Ọlọrun, nwọn si nyìn i, nitori ohun gbogbo ti nwọn ti gbọ́ ati ti nwọn ti ri, bi a ti wi i fun wọn. Nigbati ijọ mẹjọ si pé lati kọ ọmọ na nila, nwọn pè orukọ rẹ̀ ni JESU, bi a ti sọ ọ tẹlẹ lati ọdọ angẹli na wá ki a to lóyun rẹ̀ ninu.

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ