Luk 16:13-15

Luk 16:13-15 YBCV

Kò si iranṣẹ kan ti o le sin oluwa meji: ayaṣebi yio korira ọkan, yio si fẹ ekeji; tabi yio fi ara mọ́ ọkan, yio si yàn ekeji ni ipọsi. Ẹnyin kò le sin Ọlọrun pẹlu mammoni. Awọn Farisi, ti nwọn ni ojukokoro si gbọ́ gbogbo nkan wọnyi, nwọn si yọ-ṣùti si i. O si wi fun wọn pe, Ẹnyin li awọn ti ndare fun ara nyin niwaju enia; ṣugbọn Ọlọrun mọ̀ ọkàn nyin: nitori eyi ti a gbé niyin lọdọ enia, irira ni niwaju Ọlọrun.

Àwọn fídíò fún Luk 16:13-15