Luk 1:39-80

Luk 1:39-80 YBCV

Ni ijọ wọnyi ni Maria si dide, o lọ kánkan si ilẹ-òke, si ilu kan ni Juda; O si wọ̀ ile Sakariah lọ o si ki Elisabeti. O si ṣe, nigbati Elisabeti gbọ́ kikí Maria, ọlẹ̀ sọ ninu rẹ̀; Elisabeti si kún fun Ẹmí Mimọ́: O si ke li ohùn rara, o si wipe, Alabukun-fun ni iwọ ninu awọn obinrin, alabukun-fun si ni fun ọmọ inu rẹ. Nibo si li eyi ti wá ba mi, ti iya Oluwa mi iba fi tọ̀ mi wá? Sawò o, bi ohùn kikí rẹ ti bọ́ si mi li etí, ọlẹ̀ sọ ninu mi fun ayọ̀. Alabukun-fun si li ẹniti o gbagbọ́: nitori nkan wọnyi ti a ti sọ fun u lati ọdọ Oluwa wá yio ṣẹ. Maria si dahùn, o ni, Ọkàn mi yìn Oluwa logo, Ẹmí mi si yọ̀ si Ọlọrun Olugbala mi. Nitoriti o ṣijuwò ìwa irẹlẹ ọmọbinrin ọdọ rẹ̀: sá wò o, lati isisiyi lọ gbogbo iran enia ni yio ma pè mi li alabukunfun. Nitori ẹniti o li agbara ti ṣe ohun ti o tobi fun mi; mimọ́ si li orukọ rẹ̀. Anu rẹ̀ si mbẹ fun awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀ lati irandiran. O ti fi agbara hàn li apa rẹ̀; o ti tú awọn onirera ká ni ironu ọkàn wọn. O ti mu awọn alagbara kuro lori itẹ́ wọn, o si gbé awọn talakà leke. O ti fi ohun ti o dara kún awọn ti ebi npa; o si rán awọn ọlọrọ̀ pada lọwọ ofo. O ti ràn Israeli ọmọ-ọdọ rẹ̀ lọwọ, ni iranti ãnu rẹ̀; Bi o ti sọ fun awọn baba wa, fun Abrahamu, ati fun irú-ọmọ rẹ̀ lailai. Maria si ba a joko niwọn oṣù mẹta, o si pada lọ si ile rẹ̀. Ọjọ Elisabeti pe wayi ti yio bí; o si bí ọmọkunrin kan. Ati awọn aladugbo, ati awọn ibatan rẹ̀ gbọ́ bi Oluwa ti ṣe ãnu nla fun u; nwọn si ba a yọ̀. O si ṣe, ni ijọ kẹjọ nwọn wá lati kọ ọmọ na nila; nwọn si sọ orukọ rẹ̀ ni Sakariah, gẹgẹ bi orukọ baba rẹ̀. Iya rẹ̀ si dahùn, o ni Bẹ̃kọ; bikoṣe Johanu li a o pè e. Nwọn si wi fun u pe, Kò si ọkan ninu awọn ará rẹ ti a npè li orukọ yi. Nwọn si ṣe apẹrẹ si baba rẹ̀, bi o ti nfẹ ki a pè e. O si bère walã, o kọ, wipe, Johanu li orukọ rẹ̀. Ẹnu si yà gbogbo wọn. Ẹnu rẹ̀ si ṣí lọgan, okùn ahọn rẹ̀ si tú, o si sọ̀rọ, o si nyìn Ọlọrun. Ẹ̀ru si ba gbogbo awọn ti mbẹ li àgbegbe wọn: a si rohin gbogbo nkan wọnyi ká gbogbo ilẹ òke Judea. Gbogbo awọn ti o gbọ́ si tò o sinu ọkàn wọn, nwọn nwipe, Irú ọmọ kili eyi yio jẹ! Ọwọ́ Oluwa si wà pẹlu rẹ̀. Sakariah baba rẹ̀ si kún fun Ẹmí Mimọ́, o si sọtẹlẹ, o ni, Olubukun li Oluwa Ọlọrun Israeli; nitoriti o ti bojuwò, ti o si ti dá awọn enia rẹ̀ nide, O si ti gbé iwo igbala soke fun wa ni ile Dafidi ọmọ-ọdọ rẹ̀; Bi o ti wi li ẹnu awọn woli rẹ̀ mimọ́, ti nwọn ti mbẹ nigbati aiye ti ṣẹ̀: Pe, a o gbà wa là lọwọ awọn ọtá wa, ati lọwọ gbogbo awọn ti o korira wa; Lati ṣe ãnu ti o ti leri fun awọn baba wa, ati lati ranti majẹmu rẹ̀ mimọ́, Ara ti o ti bú fun Abrahamu baba wa, Pe on o fifun wa, lati gbà wa lọwọ awọn ọtá wa, ki awa ki o le ma sìn i laifòya, Ni mimọ́ ìwa ati li ododo niwaju rẹ̀, li ọjọ aiye wa gbogbo. Ati iwọ, ọmọ, woli Ọgá-ogo li a o ma pè ọ: nitori iwọ ni yio ṣaju Oluwa lati tún ọ̀na rẹ̀ ṣe; Lati fi ìmọ igbala fun awọn enia rẹ̀ fun imukuro ẹ̀ṣẹ wọn, Nitori iyọ́nu Ọlọrun wa; nipa eyiti ìla-õrùn lati oke wá bojuwò wa, Lati fi imọlẹ fun awọn ti o joko li òkunkun ati li ojiji ikú, ati lati fi ẹsẹ wa le ọ̀na alafia. Ọmọ na si dàgba, o si le li ọkàn, o si wà ni ijù titi o fi di ọjọ ifihàn rẹ̀ fun Israeli.

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ