NJẸ ija kan kò ha si fun enia lori ilẹ, ọjọ rẹ̀ pẹlu kò dabi ọjọ alagbaṣe? Bi ọmọ-ọdọ ti ima kanju bojuwo ojiji, ati bi alagbaṣe ti ima kanju wọ̀na owo iṣẹ rẹ̀. Bẹ̃li a mu mi ni oṣoṣu asan, oru idanilagãra ni a si là silẹ fun mi. Nigbati mo dubulẹ̀, emi wipe, nigbawo ni emi o dide, ti oru yio si kọja? o si tó fun mi lati yi sihin yi sọhun titi yio fi di afẹmọ́jumọ. Kòkoro ati ogulùtu erupẹ li a fi wọ̀ mi li aṣọ, àwọ mi bù, o si di sisun ni. Ọjọ mi yara jù ọkọ̀ iwunṣọ lọ, o si di lilò li ainireti. A! ranti pe afẹfẹ li ẹmi mi; oju mi kì yio pada ri rere mọ. Oju ẹniti o ri mi, kì yio ri mi mọ; oju rẹ tẹ mọra mi, emi kò sí mọ́! Bi awọ-sanma ti iparun, ti isi fò lọ, bẹ̃li ẹniti nlọ si ipò-okú, ti kì yio pada wá mọ. Kì yio pada sinu ile rẹ̀ mọ, bẹ̃ni ipò rẹ̀ kì yio mọ̀ ọ mọ.
Kà Job 7
Feti si Job 7
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Job 7:1-10
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò