JOBU 7:1-10

JOBU 7:1-10 YCE

“Ìgbésí ayé eniyan le koko, ọjọ́ ayé rẹ̀ sì dàbí ti alágbàṣe. Ó dàbí ẹrú tí ń wá ìbòòji kiri ati bí alágbàṣe tí ń dúró de owó iṣẹ́ rẹ̀. Òfo ni ọ̀rọ̀ mi látoṣù-dóṣù, ìbànújẹ́ ní sì ń dé bá mi láti ọjọ́ dé ọjọ́ Bí mo bá sùn lóru, n óo máa ronú pé, ‘Ìgbà wo ni ilẹ̀ óo mọ́ tí n óo dìde?’ Òru a gùn bí ẹni pé ojúmọ́ kò ní mọ́ mọ́, ma wá máa yí síhìn-ín, sọ́hùn-ún, títí ilẹ̀ yóo fi mọ́. Gbogbo ara mi kún fún kòkòrò, ati ìdọ̀tí, gbogbo ara mi yi, ó sì di egbò. Ọjọ́ ayé mi ń sáré ju ọ̀kọ̀ ìhunṣọ lọ, Ó sì ń lọ sópin láìní ìrètí. “Ọlọrun, ranti pé afẹ́fẹ́ lásán ni mo jẹ́, ati pé ojú mi kò ní rí ohun rere mọ́. Ojú ẹni tí ó rí mi nisinsinyii kò ní rí mi mọ́; níṣojú yín báyìí ni n óo fi parẹ́. Bí ìkùukùu tíí parẹ́ tí a kì í rí i mọ́, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀mí tí ó lọ sí ipò òkú rí, kò ní pada mọ́. Kò ní pada sí ilé rẹ̀ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni ibùjókòó rẹ̀ kò ní mọ̀ ọ́n mọ́.