Job 5:17-27

Job 5:17-27 YBCV

Kiyesi i, ibukún ni fun ẹniti Ọlọrun bawi, nitorina má ṣe gan ìbawi Olodumare. Nitoripe on a mu ni lara kan, a si di idi itura, o ṣa lọgbẹ, ọwọ rẹ̀ a si mu jina. Yio gbà ọ ninu ipọnju mẹfa, ani ninu meje ibi kan kì yio ba ọ. Ninu ìyan yio gbà ọ lọwọ ikú, ati ninu ogun yio gbà ọ lọwọ idà. A o pa ọ mọ kuro lọwọ ìna ahọn, bẹ̃ni iwọ kì yio bẹ̀ru iparun nigbati o ba dé. Ẹrin iparun ati ti iyàn ni iwọ o rín, bẹ̃ni iwọ kì yio bẹ̀ru ẹranko ilẹ aiye. Nitoripe iwọ o ba okuta ìgbẹ mulẹ̀, awọn ẹranko ìgbẹ yio wà pẹlu rẹ li alafia. Iwọ o si mọ̀ pe alafia ni ibujoko rẹ wà, iwọ o si ma ṣe ibẹ̀wo ibujoko rẹ, iwọ kì yio ṣìna. Iwọ o si mọ̀ pẹlu pe iru-ọmọ rẹ yio si pọ̀, ati awọn ọmọ-ọmọ rẹ yio ri bi koriko ìgbẹ. Iwọ o wọ isa-okú rẹ lọ li ògbologbo ọjọ bi apo-ọka ti o gbó, ti a si nko ni igbà ikore rẹ̀. Kiyesi i, awa ti nwadi rẹ̀, bẹ̃li o ri! gbà a gbọ́, ki o si mọ̀ pe fun ire ara rẹ ni!