Job 5:17-27
Job 5:17-27 Bibeli Mimọ (YBCV)
Kiyesi i, ibukún ni fun ẹniti Ọlọrun bawi, nitorina má ṣe gan ìbawi Olodumare. Nitoripe on a mu ni lara kan, a si di idi itura, o ṣa lọgbẹ, ọwọ rẹ̀ a si mu jina. Yio gbà ọ ninu ipọnju mẹfa, ani ninu meje ibi kan kì yio ba ọ. Ninu ìyan yio gbà ọ lọwọ ikú, ati ninu ogun yio gbà ọ lọwọ idà. A o pa ọ mọ kuro lọwọ ìna ahọn, bẹ̃ni iwọ kì yio bẹ̀ru iparun nigbati o ba dé. Ẹrin iparun ati ti iyàn ni iwọ o rín, bẹ̃ni iwọ kì yio bẹ̀ru ẹranko ilẹ aiye. Nitoripe iwọ o ba okuta ìgbẹ mulẹ̀, awọn ẹranko ìgbẹ yio wà pẹlu rẹ li alafia. Iwọ o si mọ̀ pe alafia ni ibujoko rẹ wà, iwọ o si ma ṣe ibẹ̀wo ibujoko rẹ, iwọ kì yio ṣìna. Iwọ o si mọ̀ pẹlu pe iru-ọmọ rẹ yio si pọ̀, ati awọn ọmọ-ọmọ rẹ yio ri bi koriko ìgbẹ. Iwọ o wọ isa-okú rẹ lọ li ògbologbo ọjọ bi apo-ọka ti o gbó, ti a si nko ni igbà ikore rẹ̀. Kiyesi i, awa ti nwadi rẹ̀, bẹ̃li o ri! gbà a gbọ́, ki o si mọ̀ pe fun ire ara rẹ ni!
Job 5:17-27 Yoruba Bible (YCE)
“Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí Ọlọrun bá bá wí, nítorí náà, má ṣe kẹ́gàn ìbáwí Olodumare. Ó ń ṣá ni lọ́gbẹ́, ṣugbọn ó tún ń dí ọgbẹ́ ẹni. Ó ń pa ni lára, ṣugbọn ọwọ́ rẹ̀ ló tún fi ń ṣe ìwòsàn. Yóo gbà ọ́ lọ́wọ́ ìnira lọpọlọpọ ìgbà, bí ibi ń ṣubú lu ara wọn, kò ní dé ọ̀dọ̀ rẹ. Ní àkókò ìyàn, yóo gbà ọ́ lọ́wọ́ ikú. Ní àkókò ogun, yóo gbà ọ́ lọ́wọ́ idà. Yóo gbà ọ́ lọ́wọ́ àwọn ẹlẹ́gàn, o kò ní bẹ̀rù nígbà tí ìparun bá dé. Ninu ìparun ati ìyàn, o óo máa rẹ́rìn-ín, o kò ní bẹ̀rù àwọn ẹranko ìgbẹ́. O kò ní kan àwọn òkúta ninu oko rẹ, àwọn ẹranko igbó yóo wà ní alaafia pẹlu rẹ. O óo máa gbé ilé rẹ ní àìséwu. Nígbà tí o bá ka ẹran ọ̀sìn rẹ, kò ní dín kan. Àwọn arọmọdọmọ rẹ yóo pọ̀, bí ewéko ninu pápá oko. O óo di arúgbó kí o tó kú, gẹ́gẹ́ bí ọkà tií gbó kí á tó kó o wá síbi ìpakà. Wò ó! A ti wádìí àwọn nǹkan wọnyi, òtítọ́ ni wọ́n. Gbọ́, kí o sì mọ̀ pé fún ire ara rẹ ni.”
Job 5:17-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Kíyèsi i, ìbùkún ni fún ẹni tí Ọlọ́run bá wí, nítorí náà, má ṣe gan ìbáwí Olódùmarè. Nítorí pé òun a máa pa ni lára, síbẹ̀ òun a sì tún dì í ní ìdì ìtura, ó sá lọ́gbẹ́, a sì fi ọwọ́ rẹ̀ di ojú ọgbẹ̀ náà jiná. Yóò gbà ọ́ nínú ìpọ́njú mẹ́fà, àní nínú méje, ibi kan kì yóò bá ọ Nínú ìyanu yóò gbà ọ́ lọ́wọ́ ikú àti nínú ogun, yóò gbà ọ́ lọ́wọ́ idà. A ó pa ọ́ mọ́ kúrò lọ́wọ́ iná ahọ́n, bẹ́ẹ̀ ní ìwọ kì yóò bẹ̀rù ìparun tí ó bá dé. Ìwọ yóò rẹ́rìn-ín nínú ìparun àti ìyàn, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì yóò bẹ̀rù ẹranko ilẹ̀ ayé. Nítorí pé ìwọ ti bá òkúta igbó mulẹ̀, àwọn ẹranko igbó yóò wà pẹ̀lú rẹ ní àlàáfíà. Ìwọ ó sì mọ̀ pé àlàáfíà ni ibùjókòó rẹ wà, ìwọ yóò sì máa ṣe ìbẹ̀wò ibùjókòó rẹ, ìwọ kì yóò ṣìnà. Ìwọ ó sì mọ̀ pẹ̀lú pé irú-ọmọ rẹ ó sì pọ̀ àti àwọn ọmọ ọmọ rẹ yóò rí bí koríko igbó. Ìwọ yóò wọ isà òkú rẹ ní ògbólógbòó ọjọ́, bí síírí ọkà tí ó gbó tí á sì kó ní ìgbà ìkórè rẹ̀. “Kíyèsi i, àwa ti wádìí rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ní ó rí! Gbà á gbọ́, kí o sì mọ̀ pé fún ìre ara rẹ ni.”