Job 37:14-24

Job 37:14-24 YBCV

Jobu dẹtisilẹ si eyi, duro jẹ, ki o si rò iṣẹ iyanu Ọlọrun. Iwọ mọ̀ akoko ìgba ti Ọlọrun sọ wọn lọjọ̀, ti o si mu imọlẹ awọsanma rẹ̀ dán? Iwọ mọ̀ ọ̀na ti awọsanma ifo lọ; iṣẹ iyanu ẹniti o pé ni ìmọ? Aṣọ rẹ̀ ti ma gbona, nigbati o mu aiye dakẹ lati gusu wá. Iwọ ha ba a tẹ pẹpẹ oju-ọrun, ti o duro ṣinṣin, ti o si dabi digi ti o yọ́ dà. Kọ́ wa li eyi ti a le iwi fun u; nitoripe awa kò le iladi ọ̀rọ nitori òkunkun. A o ha wi fun u pe, Emi fẹ sọ̀rọ? tabi ẹnikan wipe, Ifẹ mi ni pe ki a gbe mi mì? Sibẹ nisisiyi enia kò ri imọlẹ ti ndán ninu awọsanma, ṣugbọn afẹfẹ kọja, a si gbá wọn mọ́. Wura didan ti inu iha ariwa jade wá, lọdọ Ọlọrun li ọlanla ẹ̀ru-nla. Nipa ti Olodumare awa kò le iwadi rẹ̀ ri, o rekọja ni ipá, on kì iba idajọ ati ọ̀pọlọpọ otitọ jẹ. Nitorina enia a ma bẹ̀ru rẹ̀, on kì iṣojusaju ẹnikẹni ti o gbọ́n ni inu.