Job 37:14-24
Job 37:14-24 Bibeli Mimọ (YBCV)
Jobu dẹtisilẹ si eyi, duro jẹ, ki o si rò iṣẹ iyanu Ọlọrun. Iwọ mọ̀ akoko ìgba ti Ọlọrun sọ wọn lọjọ̀, ti o si mu imọlẹ awọsanma rẹ̀ dán? Iwọ mọ̀ ọ̀na ti awọsanma ifo lọ; iṣẹ iyanu ẹniti o pé ni ìmọ? Aṣọ rẹ̀ ti ma gbona, nigbati o mu aiye dakẹ lati gusu wá. Iwọ ha ba a tẹ pẹpẹ oju-ọrun, ti o duro ṣinṣin, ti o si dabi digi ti o yọ́ dà. Kọ́ wa li eyi ti a le iwi fun u; nitoripe awa kò le iladi ọ̀rọ nitori òkunkun. A o ha wi fun u pe, Emi fẹ sọ̀rọ? tabi ẹnikan wipe, Ifẹ mi ni pe ki a gbe mi mì? Sibẹ nisisiyi enia kò ri imọlẹ ti ndán ninu awọsanma, ṣugbọn afẹfẹ kọja, a si gbá wọn mọ́. Wura didan ti inu iha ariwa jade wá, lọdọ Ọlọrun li ọlanla ẹ̀ru-nla. Nipa ti Olodumare awa kò le iwadi rẹ̀ ri, o rekọja ni ipá, on kì iba idajọ ati ọ̀pọlọpọ otitọ jẹ. Nitorina enia a ma bẹ̀ru rẹ̀, on kì iṣojusaju ẹnikẹni ti o gbọ́n ni inu.
Job 37:14-24 Yoruba Bible (YCE)
“Fetí sílẹ̀, ìwọ Jobu, dúró kí o sì ronú nípa àwọn iṣẹ́ ìyanu Ọlọrun. Ǹjẹ́ o mọ bí Ọlọrun ṣe pàṣẹ, tí ó sì mú kí mànàmáná awọsanma tàn? Ǹjẹ́ o mọ̀ bí ó ṣe so awọsanma rọ̀, iṣẹ́ ìyanu ẹni tí ó pé ní ìmọ̀ ni; ìwọ tí ooru mú nígbà tí ayé dákẹ́ rọ́rọ́ nítorí pé afẹ́fẹ́ ìhà gúsù kò fẹ́? Ṣé o lè tẹ́ ojú ọ̀run bí ó ti tẹ́ ẹ, kí ó le, kí ó sì dàbí dígí tí ń dán? Kọ́ wa ní ohun tí a lè bá Ọlọrun sọ, a kò lè kó àròyé wa jọ siwaju rẹ̀, nítorí àìmọ̀kan wa. Ṣé kí n sọ fún Ọlọrun pé n ó bá a sọ̀rọ̀ ni? Ta ni yóo fẹ́ kí á gbé òun mì? “Ẹnikẹ́ni kò lè wo ìmọ́lẹ̀ ojú ọ̀run nígbà tí ó bá ń tàn ní awọsanma, nígbà tí afẹ́fẹ́ bá fẹ́ tí ó sì gbá wọn lọ. Láti ìhà àríwá ni Ọlọrun ti yọ, ó fi ọlá ńlá, tí ó bani lẹ́rù, bora bí aṣọ. Àwámárìídìí ni Olodumare– agbára ati ìdájọ́ òtítọ́ rẹ̀ pọ̀, bẹ́ẹ̀ ni kì í kọ òdodo sílẹ̀. Nítorí náà, gbogbo eniyan bẹ̀rù rẹ̀, kò sì náání àwọn tí wọ́n gbọ́n lójú ara wọn.”
Job 37:14-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Jobu, dẹtí sílẹ̀ sí èyí; dúró jẹ́ẹ́ kí o sì ro iṣẹ́ ìyanu Ọlọ́run. Ṣe ìwọ mọ àkókò ìgbà tí Ọlọ́run ṣe wọ́n lọ́jọ̀, tí ó sì mú ìmọ́lẹ̀ àwọsánmọ̀ rẹ̀ dán? Ṣé ìwọ mọ ìgbà tí àwọsánmọ̀ í fò lọ, iṣẹ́ ìyanu ẹni tí ó pé ní ìmọ̀? Ìwọ ẹni ti aṣọ rẹ̀ ti máa n gbóná, nígbà tí ó fi atẹ́gùn ìhà gúúsù mú ayé dákẹ́. Ìwọ ha ba tẹ́ pẹpẹ ojú ọ̀run, tí ó dúró ṣinṣin, tí ó sì dàbí dígí tí ó yọ̀ dà? “Kọ́ wa ní èyí tí a lè wí fún un; nítorí pé àwa kò le wádìí ọ̀rọ̀ náà nítorí òkùnkùn wa. A ó ha wí fún un pé, èmi fẹ́ sọ̀rọ̀? Tàbí ẹnìkan lè wí pé, ìfẹ́ mi ni pé kí a gbé mi mì? Síbẹ̀ nísinsin yìí ènìyàn kò rí oòrùn tí ń dán nínú àwọsánmọ̀, ṣùgbọ́n afẹ́fẹ́ ń kọjá, a sì gbá wọn mọ́. Wúrà dídán ti inú ìhà àríwá jáde wá; lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni ọláńlá ẹ̀rù ńlá wa. Nípa ti Olódùmarè àwa kò le wádìí rẹ̀, ó rékọjá ní ipá; nínú ìdájọ́ àti títí bi òun kì í ba ẹ̀tọ́ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ òtítọ́ jẹ́. Nítorí náà ènìyàn ha máa bẹ̀rù rẹ̀, òun kì í ṣe ojú sájú ẹnikẹ́ni tí ó gbọ́n ní ayé?”