Job 3:2-5

Job 3:2-5 YBCV

Jobu sọ, o si wipe, Ki ọjọ ti a bi mi ki o di igbagbe, ati oru nì, ninu eyi ti a wipe; a loyun ọmọkunrin kan. Ki ọjọ na ki o jasi òkunkun, ki Ọlọrun ki o má ṣe kà a si lati ọrun wá, bẹ̃ni ki imọlẹ ki o máṣe mọ́ si i. Ki òkunkun ati ojiji ikú fi ṣe ti ara wọn: ki awọsanma ki o bà le e, ki iṣúdùdu ọjọ na ki o pa a laiya.