Job 3:2-5
Job 3:2-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
Jobu sọ, o si wipe, Ki ọjọ ti a bi mi ki o di igbagbe, ati oru nì, ninu eyi ti a wipe; a loyun ọmọkunrin kan. Ki ọjọ na ki o jasi òkunkun, ki Ọlọrun ki o má ṣe kà a si lati ọrun wá, bẹ̃ni ki imọlẹ ki o máṣe mọ́ si i. Ki òkunkun ati ojiji ikú fi ṣe ti ara wọn: ki awọsanma ki o bà le e, ki iṣúdùdu ọjọ na ki o pa a laiya.
Job 3:2-5 Yoruba Bible (YCE)
Ó ní: “Ègún ni fún ọjọ́ tí wọ́n bí mi, ati alẹ́ tí wọ́n lóyún mi. Jẹ́ kí ọjọ́ náà ṣókùnkùn biribiri! Kí Ọlọrun má ṣe ka ọjọ́ náà sí, kí ìmọ́lẹ̀ má ṣe tàn sí i mọ́. Ṣe é ní ọjọ́ ìṣúdudu, ati òkùnkùn biribiri. Kí ìkùukùu ṣíji bò ó, kí òkùnkùn sì dẹ́rù bà á.
Job 3:2-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Jobu sọ, ó sì wí pé: “Kí ọjọ́ tí a bí mi kí ó di ìgbàgbé, àti òru ni, nínú èyí tí a wí pé, ‘A lóyún ọmọkùnrin kan!’ Kí ọjọ́ náà kí ó já si òkùnkùn, kí Ọlọ́run kí ó má ṣe kà á sí láti ọ̀run wá; bẹ́ẹ̀ ni kí ìmọ́lẹ̀ kí ó má ṣe mọ́ sí i. Kí òkùnkùn àti òjìji ikú fi ṣe ti ara wọn; kí àwọsánmọ̀ kí ó bà lé e; kí ìṣúdudu ọjọ́ kí ó pa láyà.