Joh 8:28-36

Joh 8:28-36 YBCV

Nitorina Jesu wi fun wọn pe, Nigbati ẹ ba gbé Ọmọ-enia soke, nigbana li ẹ o mọ̀ pe, emi ni, ati pe emi kò dá ohunkohun ṣe fun ara mi; ṣugbọn bi Baba ti kọ́ mi, emi nsọ nkan wọnyi. Ẹniti o rán mi si mbẹ pẹlu mi: kò jọwọ emi nikan si; nitoriti emi nṣe ohun ti o wù u nigbagbogbo. Bi o ti nsọ nkan wọnyi, ọ̀pọ enia gbà a gbọ́. Nitorina Jesu wi fun awọn Ju ti o gbà a gbọ́ pe, Bi ẹnyin ba duro ninu ọ̀rọ mi, nigbana li ẹnyin jẹ ọmọ-ẹhin mi nitõtọ. Ẹ ó si mọ̀ otitọ, otitọ yio si sọ nyin di omnira. Nwọn da a lohùn wipe, Irú-ọmọ Abrahamu li awa iṣe, awa kò si ṣe ẹrú fun ẹnikẹni ri lai: iwọ ha ṣe wipe, Ẹ o di omnira? Jesu da wọn lohun pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹnikẹni ti o ba ndẹṣẹ, on li ẹrú ẹ̀ṣẹ. Ẹrú kì si igbé ile titilai: Ọmọ ni igbe ile titilai. Nitorina bi Ọmọ ba sọ nyin di omnira, ẹ ó di omnira nitõtọ.

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ