Jesu tún wí fún wọn pé, “Nígbà tí ẹ bá gbé Ọmọ-Eniyan sókè, nígbà náà ni ẹ óo mọ̀ pé èmi ni, ati pé èmi kò dá ohunkohun ṣe fúnra mi, ṣugbọn bí Baba ti kọ́ mi ni mò ń sọ̀rọ̀ yìí. Ẹni tí ó rán mi níṣẹ́ wà pẹlu mi, kò fi mí sílẹ̀ ní èmi nìkan, nítorí mò ń ṣe ohun tí ó wù ú nígbà gbogbo.” Nígbà tí Jesu sọ ọ̀rọ̀ báyìí, ọpọlọpọ eniyan gbà á gbọ́. Jesu bá wí fún àwọn Juu tí ó gbà á gbọ́ pé, “Bí ẹ̀yin bá ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ mi, ọmọ-ẹ̀yìn mi ni yín nítòótọ́; ẹ óo mọ òtítọ́, òtítọ́ yóo sì sọ yín di òmìnira.” Wọ́n sọ fún un pé, “Ìran Abrahamu ni wá, a kò fi ìgbà kan jẹ́ ẹrú ẹnikẹ́ni. Kí ni ìtumọ̀ gbolohun tí o wí pé, ‘Ẹ̀yin yóo di òmìnira’?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ẹnikẹ́ni tí ó bá ń dẹ́ṣẹ̀, ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ ni. Ẹrú kì í gbé inú ilé títí, ọmọ níí gbé inú ilé títí. Nítorí náà, bí Ọmọ bá sọ yín di òmìnira, ẹ óo di òmìnira nítòótọ́.
Kà JOHANU 8
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: JOHANU 8:28-36
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò