Jak 5:10-12

Jak 5:10-12 YBCV

Ará mi, ẹ fi awọn woli ti o ti nsọ̀rọ li orukọ Oluwa ṣe apẹrẹ ìya jijẹ, ati sũru. Sawò o, awa a mã kà awọn ti o farada ìya si ẹni ibukún. Ẹnyin ti gbọ́ ti sũru Jobu, ẹnyin si ri igbẹhin ti Oluwa ṣe; pe Oluwa kún fun iyọ́nu, o si ni ãnu. Ṣugbọn jù ohun gbogbo lọ, ará mi, ẹ máṣe búra, iba ṣe ifi ọrun búra, tabi ilẹ, tabi ibura-kibura miran: ṣugbọn jẹ ki bẹ̃ni nyin jẹ bẹ̃ni; ati bẹ̃kọ nyin jẹ bẹ̃kọ; ki ẹ má bã bọ́ sinu ẹbi.