JAKỌBU 5:10-12

JAKỌBU 5:10-12 YCE

Ẹ̀yin ará, ẹ wo àpẹẹrẹ àwọn wolii, àwọn tí wọ́n sọ̀rọ̀ ní orúkọ Oluwa pẹlu sùúrù ninu ọpọlọpọ ìpọ́njú. Ẹ ranti pé àwọn tí ó bá ní ìfaradà ni à ń pè ní ẹni ibukun. Ẹ ti gbọ́ nípa Jobu, bí ó ti ní ìfaradà, ẹ sì mọ bí Oluwa ti jẹ́ kí ó yọrí sí fún un. Nítorí oníyọ̀ọ́nú ati aláàánú ni Oluwa. Boríborí gbogbo rẹ̀, ẹ̀yin ará mi, ẹ má máa búra, ìbáà ṣe pé kí ẹ fi ọ̀run búra, tabi ilẹ̀, tabi ohun mìíràn. Tí ẹ bá wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni,” bẹ́ẹ̀ gan-an ni kí ó jẹ́. Bí ẹ bá wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́,” kí ó jẹ́ “Bẹ́ẹ̀ kọ́.” Kí ẹ má baà bọ́ sinu ìdájọ́.