Jak 1:9-11

Jak 1:9-11 YBCV

Ṣugbọn jẹ ki arakunrin ti iṣe talaka mã ṣogo ni ipo giga rẹ̀. Ati ọlọrọ̀, ni irẹ̀silẹ rẹ̀, nitori bi itanná koriko ni yio kọja lọ. Nitori õrun là ti on ti õru mimu, o si gbẹ koriko, itanná rẹ̀ si rẹ̀ danu, ẹwà oju rẹ̀ si parun: bẹ̃ pẹlu li ọlọrọ̀ yio ṣegbe ni ọ̀na rẹ̀.